Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,148,915 members, 7,802,979 topics. Date: Saturday, 20 April 2024 at 06:21 AM

Ogun Awon Bàba Wa - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Ogun Awon Bàba Wa (325837 Views)

Asiri Aiye Siwa Lowo Awon Agba Woli / Asiri Ijinle Awon Woli Lailai / Asiri Ogun Awon Baba Wa (2) (3) (4)

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (Reply) (Go Down)

Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:19pm On Dec 04, 2015
moki gbogbo omo Yoruba mosi ikanni yi fun afani opolopo omo odudua fun Ogun nla Awon baba wa ni ile karo ojire ti o ti sonu ti Ati sodi ohun igbagbe ti awon alawo funfun si fi etan ati owo gba kuro lowo wa,esin o sope ka ma se ASA ibile wa o,omo Yoruba eje karonu o,Ikilo mi o fi aiye gba enikeni lori ikanni yi fun oro ti koye omo Yoruba tabi ebu iwa ibaje fifi ago ibanisoro sori afefe,atipe oun gbogbo tabafe ko si ori afefe komu ogbon dani kosi wulo fun Awon eniyan ki o si ma pawonlara odua agbe wa o

3 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:49pm On Dec 04, 2015
moki gbogbo omo Yoruba pe aku dede asikoyi o a si ku ojonla Jimo toni koni je ase mo wa o,esin kan o sope kama se ajo o,oun ta lo gba wa lati ile ajeji ema je kopa ti awon baba wa Lara o,mi sope ki a ma sin olorun Oba okan soso o,eledunmare o,sugbon karanti pe larubawa ni asa Ati itoju ara nipa ilane tiwon won o parun o,Israeli na be,oyibo alawo funfun na,ki omo Yoruba madi atemere lagbaye Ati ki iya maje wa mo ni mose sin ikanni yi o,Ohun gbogbo ti o Ba je ododo le ma ri lati Odo mi,tikosini ni ipalara,be ni mosi fe ki gbogbo away taba darapo mo ikanni yi Na ma se,karanti pe eni riwatan to mo korowa iwo wa o,so ododo fun enikejire oje Idunnu eledunmare ESE ewe amaje Ogun ama je o odua agbe wa o Ase.

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:59pm On Dec 04, 2015
OGUN APAGUN
Ori ako pepeye itana igi ose toresile,odidi atare kan aojopo ao ma fi fo eko tutu Mu,o ma pa Ogun buburu ninu ara ni o da ju

5 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 2:14pm On Dec 04, 2015
OGUN IWOSAN AYE
ewe ela,ewe alupayida odidi atare kan, ao jo po ao da sinu omori isaasun ao wa ko oruka irin si,ao wa da epo pupa si ao ro po, ao wa fa Ogun yan si enu akuko adie,ni emeta,ao ma fi oruka ni si lenu ni okokan yio ma gbemi,ti o bawa di OJO keje ao pa adie na,ao lainure ao Ba awon oruka na,ao ko ao ma fun eniti Asian ba nse yio fi bowo re,aisan re yio San ni OJO na ase eledunmare ni,iba eyin agba o aiye mojuba o,mowole mo pa igbunmo o,mofori bale fun gbogbo ajunilo.

7 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 6:59pm On Dec 04, 2015
eku dede asikoyi o Mo wipe eleda wa koni gba abodi o
Re: Ogun Awon Bàba Wa by enigstil(m): 7:18pm On Dec 04, 2015
Aboru boye o, eku ise o, Oduduwa agbe wa o, bawo ni moshe le kan si yin o
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:32pm On Dec 04, 2015
enikeni ti o ba ni oro ida konko lati bami so Ki o kan simi lori (prophet.nase.Solomon10@gmail.com) tabi whatsapp 08135072961 tabi 07087811181,abanise a ba wa se tiwa o amin

3 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:54pm On Dec 04, 2015
OGUN TAFI WE ISE OSI DANU
Ao toju odidi ori etu kan,iye agbe meta,iye aluko meta,ikode meta,iye lekeleke meta,iye akala meta,iye igun meta,iye awodi meta,ao Jo po pelu atare odidi kan,ao po Mo ose,ao kosinu igba olomori,ao te ifa osa meji si lori,ao ma fi we,ao bere si ri se,iba eyin agba o.

8 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 9:35pm On Dec 04, 2015
Gbogbo eniyan ti eledumare fun ni imo nipa tewetegbo to je,lo lefi Ogun ajo toni afani fun ilo gbogbo Omo odua si ori ikanni yi o,kasi Jo yara ni ogbon Awon baba wa,ewe ama je o

2 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Snowealth: 10:42pm On Dec 04, 2015
E ku ise baba, Eledumare a tun bo ma fun yin se o.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Snowealth: 10:47pm On Dec 04, 2015
ayokomi1010:
OGUN IWOSAN AYE
ewe ela,ewe alupayida odidi atare kan, ao jo po ao da sinu omori isaasun ao wa ko oruka irin si,ao wa da epo pupa si ao ro po, ao wa fa Ogun yan si enu akuko adie,ni emeta,ao ma fi oruka ni si lenu ni okokan yio ma gbemi,ti o bawa di OJO keje ao pa adie na,ao lainure ao Ba awon oruka na,ao ko ao ma fun eniti Asian ba nse yio fi bowo re,aisan re yio San ni OJO na ase eledunmare ni,iba eyin agba o aiye mojuba o,mowole mo pa igbunmo o,mofori bale fun gbogbo ajunilo.
E jowo baba, oruka melo ni a ma lo? A ju yin se o.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 3:35am On Dec 05, 2015
oruka bi meta tabi Meje lama lo fun Ogun na

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Snowealth: 9:34am On Dec 05, 2015
ayokomi1010:
oruka bi meta tabi Meje lama lo fun Ogun na
E seun pupo, mo dupe o.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 10:37am On Dec 05, 2015
e karo gbogbo Omo odudua,ojumo ayo loni ma je fun wa o
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 12:05pm On Dec 05, 2015
[i][/i]Baba, eku ise, edumare yio ma ran yin lowo. E jor sir. Ajegun ati ebe awon agba ni emi nfe.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:30pm On Dec 05, 2015
OGun AJEGUN.
ao toju oga aye kan,ao fi ako Okuta ge iru oga na ni aye,ao lo pelu omo atare mesan,ao fi si gbere yipo owo mejeji. o daju.

4 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:08pm On Dec 05, 2015
OGUN EBE AWON AGBA
obi pupa kan,funfun kan,ewe ata ijosi,ao gun Mo ose ao mawe.
(²) igbin kan,odu ori ewe ahunekun,epo obo,ao gun dada ao fi ose po ao ko sinu aso funfun,wiwe ni odaju

5 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Snowealth: 8:11pm On Dec 05, 2015
ayokomi1010:
OGun AJEGUN.
ao toju oga aye kan,ao fi ako Okuta ge iru oga na ni aye,ao lo pelu omo atare mesan,ao fi si gbere yipo owo mejeji. o daju.
E kaale Baba, e jowo to ba se wipe obinrin ni o fe lo ise yii, se atare mesan naa lo ma lo ni tabi meje. E jowo, e la mi lo ye. Mo dupe o. Eledua a ma ran yin lowo o.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 11:00pm On Dec 05, 2015
ayokomi1010:
OGUN EBE AWON AGBA
obi pupa kan,funfun kan,ewe ata ijosi,ao gun Mo ose ao mawe.
(²) igbin kan,odu ori ewe ahunekun,epo obo,ao gun dada ao fi ose po ao ko sinu aso funfun,wiwe ni odaju
E jor. Kilo nje ''ODU ORI EWE AHUNEKUN''?

2 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Ayomidegbenga1(m): 11:01am On Dec 06, 2015
E jowo baba, e fun mi ni ogun Aleko todaju.Ewe a maa je fun yin ooo...Ase

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:27am On Dec 07, 2015
e karo,aku ojumo rere o, Awon baba wa Ni iwure yi dara pupo Lati ma lo ni owuro kutu papa julo OJO aje, Ao bu OMI tutu sinu igba kan tabi Awo,ao te ejiogbe si ori omi na,ao wa wure yisi,lehin na la o mu die nibe ao da iyoku sile ni enu ona ile wa ao fi ese alafia te mole bo sita,Iwure:-) OMI sepesepe nise OMI alaketu,agbara gbururu nise OMI ete ife,o dara fun eyin aja eyin aja funfun nini,o dara fun OMI iyirisi OMI iyirisi ntan yiriyiri,nje o ori wa di ori Ade loni o,orun wa di orun ileke ola,ESE wa di ESE bata ola loni,nitoripe ojukan ti oka Ba joko si lohunje oka lo Ba oka,ojukan ti ere jokosi ni ohunje ere ba ere,ojumo Ki Mo Ki adariwurun ma bere OMI,ejiogbe o sebi odu mererindilogun ni se erusin fun ejiogbe,Ki won wa fi oun rere sin mi loni o,kiri aje se ohun rere.Ase ase ase . ! kabiyesi eledumare oba ajiki o,aiye toto akamora iba o,ire ni mase nitemi Omo obasayero,mi o Ni se ika,sugbon bi aye bawa so ire di ibi ipade di ohun o.

4 Likes 2 Shares

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:34am On Dec 07, 2015
Ajegun yan,Omo atare Meje ni fun obinrin,mesan ni fun okunrin

1 Like 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 8:38am On Dec 07, 2015
Ebe Awon agba yan,ohun toje odu ori ewe ahunekun ni ESO tobawa Lori ewe egele,ti a tunpeni mafiowokan Omo mi.

4 Likes

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 12:53pm On Dec 09, 2015
Owo ati aponle ni mofi kiyin. E jor sir, ti awon customer wa ko ni fi lo. Tafi mun customer. Efun wa sir.[s][/s]
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 11:49pm On Dec 13, 2015
[sup][/sup][color=#000099] Se e ti ti ile yi pa ni?
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:14pm On Dec 17, 2015
OGUN Ti AFI MADE ONI JALABI MOLE
ao wa ewe omisimisi,ao gun mo ose ao fi ito ti aba ko to laro po,ati ito enuwa toje ti owuro kutu,lehin ti a po tan ,ao ma bu fun Awon to wa sodowa ki o mafiwe,Gbogbo Igba tiwa nikan ni won mari ro.
2)eiyele kan ao la ni aya,ao ko ewe abo 9 si,ati ewe amunimuye die,okun sokoto wa,odidi atare kan,ao jopo,kama funwon lo die die.

3 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 1:49pm On Dec 17, 2015
OSOLE OWO NLA
ao toju odidi okete kan ,opolopo ewe ewuro,tagiri odidi kan,Gbogbo owo tane,odidi atare kan,ao jo po ,ao mafi eyin adie ibile je lekan lojumo

3 Likes 1 Share

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 9:16pm On Dec 17, 2015
ayokomi1010:
OGUN Ti AFI MADE ONI JALABI MOLE
ao wa ewe omisimisi,ao gun mo ose ao fi ito ti aba ko to laro po,ati ito enuwa toje ti owuro kutu,lehin ti a po tan ,ao ma bu fun Awon to wa sodowa ki o mafiwe,Gbogbo Igba tiwa nikan ni won mari ro..
Baba. E seun fun ise yi.
2)eiyele kan ao la ni aya,ao ko ewe abo 9 si,ati ewe amunimuye die,okun sokoto wa,odidi atare kan,ao jopo,kama funwon lo die die.

1 Like 2 Shares

Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 11:34pm On Dec 17, 2015
ayokomi1010:
OSOLE OWO NLA
ao toju odidi okete kan ,opolopo ewe ewuro,tagiri odidi kan,Gbogbo owo tane,odidi atare kan,ao jo po ,ao mafi eyin adie ibile je lekan lojumo
gege bi o se ye mi, se ebu die lao ma bu fi din eyin kokan lojojumo abi ni idakureku?

1 Like

Re: Ogun Awon Bàba Wa by ALIUDAVID: 1:24pm On Dec 18, 2015
Baba o ejo efi email tabi phone number yin sita..
Baba efun wa ni ogun (AWORAN) tabi (OHUMO) ti Afin wo inkan ATI (ATUPA-AYE) iba eyin agbagba, iba aye.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by Shomar: 3:00pm On Dec 18, 2015
Gege bi Oruko yin. Ayo koni won ni ile yin. E jor sir. E fun wa ni ogun lagunlagun todaju.
Re: Ogun Awon Bàba Wa by ayokomi1010(m): 7:25pm On Dec 18, 2015
OGUN OSOLE YAN
ao ma bu diedie la o mawa se eyin adie ibile kan lojumo,ti a ba tise eyin tojina tan ao bo epo re,ao mawa Fi eyin yan ba etu-ogun tajo yan je,be lase malo o

6 Likes 2 Shares

(1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (Reply)

Meet The Most Beautiful People On Earth- The Fulanis / Post Pictures Of Traditional Weddings. / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 72
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.