Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,158,739 members, 7,837,674 topics. Date: Thursday, 23 May 2024 at 09:15 AM

Itan Alajo Somolu - Literature - Nairaland

Nairaland Forum / Entertainment / Literature / Itan Alajo Somolu (2727 Views)

Itan Sebi Otimo / Itan Akonilogbon / "somolu Blues"- Who Is The Author/writer Of This Book? (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Itan Alajo Somolu by oloriireomo(m): 6:07pm On Sep 11, 2013
Alajo Somolu

Bi a bá r'enikan t'o ja fafa, a maa nso pé ori e pé bi ori baba Alájo Shomolu to ta mótò ra keke, to gba ajo l’owo eédégbeta eniyan láì wo ìwé, o da owo onikaluku pada láì si owó san f’enikankan.

Ta a ni Alajo Somolu gan?
Sàsà ènìyàn ló mò pé, èèyàn gidi ni Alajo Somolu ti won maa ns’òrò è yi, kii se eni inu ìtàn aroso rara.

Ni odun 1915, ni Isonyin Ijebu, obinrin kan bi ibeta ni asiko to jé pe nkan ìbèrù ati kàyéfì ni ki eeyan bi ju omo kan lo.
Nitori àsà ìgbàanì, ààyè ni won sin Etaòkò, won fi se ètùtù ki awon alálè o lè f’iyedénú. Ko pé si asiko yi naa ti Kehinde lo ra aso wa, o ku Taiwo nikan s’áyé.

Oju Taiwo ri èélááfí. Odomode ló wà ti baba rè fi s’ílè bora bi aso. Nigba ti kò si ònà lati ka iwe jinna, Taiwofi Isonyin Ijebu silè, o wa ise aje lo si Eko Akete. O fi ara rè si èkósé aránso nigba tó de Eko.

Taiwo kósé ó mo’sé, kó ná ìná àpà ó ra okò akérò. Laipe, o fi okò wiwà silè ó bèrè esúsú tabi ajo ojúmó. Taiwo ta oko akero yi, o ra kèké ológeere nitori kèké lo lè maa gbe lo si gbogbo ibi ti awon olójà to nsan esúsú wà.
Ki ni Taiwo rò de ibi ajo gbigba? Awon ile ifowopamo to wa l’asiko yi ò ri ti awon iyalójà ati babalójà gbó, awon ile ise nla nla ni onibaràwon.

Taiwo bere sii gba èsuntéré owó ajo ojumo l’owo awon mekúnnù olójà, o nko fun won kìtí n’íparí osù. O nyá won l’owo lai gba dukia kankan fun iduro.
Bi eré bi eré, òkòwò èsúsú yi ngbilè, béè ni ojà awon onibara rè naa ngbèrú si. Taiwo di ayànfé gbogbo olójà, o di ìlúmòká alájo ojúmó. Ibi ti ounti a mò si Ile ifowopamo Mekunnu l’oni ti bere ni yen.
"Awon agbègbè tó jé àrésèpa fun Taiwo ni Sangross, Baba Olóòsà, Ojúwòyè, Awolowo, Oyingbo, Olaleye ati Shomolu,gbogbo oja ati agbègbè ti a daruko yi ni Taiwo ti ngba àjo. Awon onibara re feran rewon si f’inu tan tori won ò ri ki Taiwo ó fi dúdú pe funfun fun won.
Alakori kii s’egbe alakowe nigba naa. Ko si erò isirò ti a mo si calculator, sugbon ori Taiwo pé, o ns’isé bi aago ni. Láì wo iwe akosílè, Taiwo a má a so iye ti enikookan ti dá si òun lówó.

Bi enikeni sì ba Taiwo jiyan, nigba ti won ba jo gbé gègé le isiro, won a gba fun Taiwo kehin naa ni tori bo bá se wi pe o ri naa ni won ó ba a.

Gbogbo awon onibara rè ló féki omo won o ni ori pipe bii Taiwo, won a si maa fi se akawe pe, ‘Ori omo mi pe bi ti Baba Alajo Somolu”,
Itan baba Alajo Somolu yi fi han wa bi aye se dara to ni asiko yen, kò si jìbìtì.

Se awon eniyan kó ni won da ile ifowopamo sile ti won so ara won di eku òfónòn si wa l’orun, awon èèkàn inu ijo Olorun ti Oniwaasu nwárí fun? Taiwo fi igboya, oyaya, ati otito inu se ise re lai ri awokose kankan, ó si di eekan pataki ninu itan ile Yoruba ti a nfi oruko rè suref’omo eni.
Ninu ikoko dudu l’eko funfun ti njade.
Baba Alajo Somolu wo sakun òrò, o woye nkan ti awon arailu nilò, lai ri iranlowo ijoba tabi ti olówó kan, o pakiti mole, pelu ifojúsùn ati èrò peatelewo eni kii tan’ni í je, o tiipa béè gba aimoye idile l’ówóebi ati ìsé, o gba mekúnnù l’owo awon agbàlówóméèrí ileifowópamo, ó ti ipa béè di olokiki eniyan titi ti oro re fi di àsà ti a ndá.

Taiwo Olunaike fi oruko to dara silè de omo ati àrómodómo rè. Titi ayé, ti àsà ati èdè Yoruba ba si nwà, a ò ni yé so fun eni ti ori è pé wipé “Ori è pe bi ori Alajo Somolu”. Oruko wo ni iwo fé fi silè de awon iran tó nbò l’éyìn? Se eèkàn ni o ninu isekuse, àjààgbilà, isokúso, iwa olè, kenimání, jandùkú, ati gbogbo iwà buruku ayé? Ki tie ni èkó ti iwo nkó omo re? Ki ni aládúgbò nwi nipa re?
Tulétúlé ni o abi Atúnlútò? Oba to je ti ilú tòrò ati eyi to je ti ilú dàrú, oruko won ò ni jo pare ni, sugbon ki ni a ó so nipa ti iwo?
Nje kò ye ki a kó ogbón nla ninu itan Taiwo Olunaike yi paapaa ni asikò ti isé wón bi imí eégún ni orile èdè Naijiria, ti awon omo wa ti m’órí lé òkè òkun tán. Ohun tielòmíìn nwa lo si sokoto nbe ni apo sokoto re.
Awon olójà ò kuku ke gbàjarè lo s’ilé oba béè ni won ò ké gbàmí gbàmí to Taiwo Olunaike, sugbon òun de oju silè, o fi riimu. Làákàyè ti Taiwo Olunaike lò kii se eyi ti a kó oni ilé ìwé, ogbón inú l’ejò fi ng’àgbon. Njé ìwo ò ma f’oju témbélú orisirisi ànfààni to wa ni igi imu re nitori ìgberaga ati ìwà òle? Ki ni o lè se lati ran ilú tabi adúgbò re l’ówó?

1 Like

(1) (Reply)

List Of Nigerian Literary Blogs / Sites You Can Submit Your Works For Free. / FEDDIE GIRL Novel: For all ex-boarding school students. Check this out!!!!!! / Soliloquies: Diary Of An Assistant Girlfriend

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 19
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.