Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,559 members, 7,816,355 topics. Date: Friday, 03 May 2024 at 10:05 AM

PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile (1639 Views)

Ope O! Ijoba Ipinle Osun Ti F'owo Si Sisan Owo Awon Osise / Ni Ipinle Oyo, Owo Awon Olopa Ti Ba Awon Afurasi L'ebo-l'oogun Merin / Interesting Things About 'The Iku Baba Yeye Of Yoruba Land': Oba Lamidi Adeyemi (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by obaede: 10:58pm On Dec 17, 2014
Awon Omo Egbe PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile Pelu Bo Se Padanu Ipo Igbakeji Buhari
www.olayemioniroyin.com

Awon omo egbe PDP ti Ipinle Rivers ti ko leta "O Ku Ori Ire" ranse si Gomina Ipinle naa, Rotimi Amaechi eleyii ti won fi n se yeye pelu bi ipo igbakeji Buhari se bo mo lowo.

Won ni pelu gbogbo lalakukufefe re, lori looser naa ni oro re pada jasi. Gege bi atejade won se so, "aimoye owo Ipinle naa ni Amaechi n na yafunyafun lati wa oju ire awon agbaagba egbe APC tori ki won le gbe ipo igbakeji Buhari fun un. Sugbon ori ti won ti ko iya mo latorun loro re, ko ni sa lai ma jeya naa."

Won tun fi kun wi pe a se ori Amaechi kosi nibe rara, enu lasan lo ni bi ajakara. " Elenu yiyo bi ila, a fi igba to pada lana".

Sugbon ninu iroyin mii to jade, ohun ti a gbo ni wi pe oseese ki won wa ipo to ni kimi kan fun Rotimi Amaechi ninu ijoba Buhari leyin to ba wole. Ipo ti won si n foju sun naa ni akowe agba patapata fun ijoba apapo iyen ti Buhari ba le se bee gbori wo Aso Rock l'Abuja.

Ninu iroyin mii: Awon omo irapada (RCCG) ti bere si ni fi adura ran Paito Yemi Osinbajo lowo pelu bi Olorun Emi Mimo se n sin lo si ibi giga. Bi won se n korin Hallelujay ti won dunnu bee ni won ran Paito leti ise pataki ti awon omo Nigeria fe ki won se leyin ti won ba wonu ogo lo.

Ninu Iroyin mii: Nje e ti gbo wi pe Musiliu Obanikoro ti gbe Jimi Agbaje lo si ile ejo to gaju lo latari ibo abele to waye eleyii ti Agbaje jawe olubori. Obanikoro so wi pe ojoro ni ibo to kede Agbaje gege bi olubori.

Nibayii ile ejo to gaju ni ilu Abuja ti ranse pe egbe PDP ati INEC lati wa so ohun ti won ri lobe ti won fi waru sowo ni ile ejo lojo ketalelogun osu kejila odun yii (Dec 23).

Bakan naa, ile ejo ti pase wi pe egbe PDP Ipinle Eko ko gbodo gbe igbese kankan lori idibo to waye tele ayafi ti ile ejo ba yanju gbogbo oro naa patapata.

E tun gba iroyin kekere yii kun tile: Akolawole Olootu, ogbontarigi sorosoro ni ile Adulawo ti ki Taye Currency to je okan pataki ninu awon omo olorin fuji to fi ilu Ibadan se ibujoko ku orire ayajo ojo ibi re to ko lonii [17-12-14]. Igba odun, odun kan ni!

Nje e ti gbo? Awon Boko Haram ti gbe Fidio tuntun kan jade bayii nibi ti Shekau ti n leri wi pe oun yoo seku pa Emir ti ilu Kano. Shekau to je olori awon Boko Haram so wi pe enu Emir ti gbooro ju, awon si ti setan lati ko logbon gidigidi.
http://www.olayemioniroyin.com/2014/12/awon-omo-egbe-pdp-ti-ipinle-rivers-ti.html

http://www.facebook.com/photo.php?fbid=747607288658490&set=gm.889504514434192&type=1&relevant_count=1

Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by 2prexios: 11:18pm On Dec 17, 2014
Sokoto tobale lomo araye nri, aye i bani ri wahala eni o dami loju, aye binu kaun won so kaun somi... To Ololajulo Amechi, ori yin a sinyin lo sibi ire o. Nse ni kee roju d'opin: eni ti o le sebi alaaru l'Oyigbo, ko le se bi Adejoro loja Oba. Eyin omo Ijo Irapada, awa ju asegun lo. Alagba Obaede, eku ifomoniyan se o. Aa~juse fun gbogbo wa o, ase.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by obaede: 4:03am On Dec 18, 2014
Ase!
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by Nobody: 9:31pm On Dec 18, 2014
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by 2prexios: 10:24pm On Dec 18, 2014
Zeemoor:
Zeemor, orekelewa mi, se alaafia l'owa, gege bi emi naa ti wa nihin? Eku airini, aibeere eni o. A kuu imurasile odun keresi.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by Nobody: 7:02am On Dec 19, 2014
Alafia ni mo wa jare
Eku keresi in advance
2prexios:
Zeemor, orekelewa mi, se alaafia l'owa, gege bi emi naa ti wa nihin? Eku airini, aibeere eni o. A kuu imurasile odun keresi.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by 2prexios: 4:14pm On Dec 19, 2014
Zeemoor:
Alafia ni mo wa jare
Eku keresi in advance
Awa re we. Iwoyi amodun, ire owo ire omo ati aiku baale oro, a maa je tie arabinrin mi. Mo yo fun e, mo yo funra mi.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by Nobody: 4:21pm On Dec 19, 2014
Ermm.....
English, please grin
2prexios:
Awa re we. Iwoyi amodun, ire owo ire omo ati aiku baale oro, a maa je tie arabinrin mi. Mo yo fun e, mo yo funra mi.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by 2prexios: 4:47pm On Dec 19, 2014
Zeemoor:
Ermm.....
English, please grin
A ko gbodo so ede miran l'agbo yi yato si abinibi. Aijebe, gbado gbado maa fe gbowo agbado lowo enikan o.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by 2prexios: 5:59pm On Dec 19, 2014
Zeemoor:
Ermm.....
English, please grin
Agbo abinibi lawa o.
Re: PDP Ti Ipinle Rivers Ti Da Yeye Rotimi Amaechi Sile by Nobody: 10:10pm On Dec 19, 2014
undecided
2prexios:
A ko gbodo so ede miran l'agbo yi yato si abinibi. Aijebe, gbado gbado maa fe gbowo agbado lowo enikan o.

(1) (Reply)

Why Do Ibadan People Call Every Tall Guys Daddy? / Beautiful Pictures Of Northern Nigeria The Media Never Shows You / The Statue Of Liberty Is Originally The Statue Of Moremi By Ooni Of Ife.

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 24
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.