Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,153,966 members, 7,821,392 topics. Date: Wednesday, 08 May 2024 at 12:21 PM

Yoruba Hymn - Religion - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Yoruba Hymn (9381 Views)

Story Behind The Hymn, "When I Survey The Wondrous Cross" / Which Church Has The Best Hymn Songs / What Is Your Favourite Hymn? (2) (3) (4)

(1) (Reply) (Go Down)

Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:44am On Sep 28, 2016
Ko tun si ore bi Jesu,
Eniti o ru gbogbo ese wa,
T’o ku iku Oro fun wa ni aikanra.
Ore Nla
Ife nla alailegbe (2ce)
Ni ti Jesu, Olugbala rere

Ife l'O fi ku f'aw'elese
Eni t'O farada irora
Taraiye pa, n'irira
l'aide ri, Ore nla?

Ani'ku reyi j'Ebo fese
Etu t'O se tun je ailegbe
O to k'awa k'o feran
Jesu jojo; Ore nla!

Ileri Re nfun okan layo
Eni to far a gba iya wa
T'O je k'awa k'o gba
Ifiji t'Oba; Ore nla!

Ko siru aini to nje ni n'ya
Baba l'o run kappa 're jojo
O to k'awa wa do 're
Fun isinmi, Ore nla!

Ko to kawa ko ko ife 're
Oba t'o j'oba lo ma ni o
Dupe pe ina fe Re yi
Ki jo ku; Ore nla
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 10:42am On May 29, 2017
The correct lyrics

Fun anu to po bi'yanrin
Ti mo ngba lojumo
Lat'odo Jesu Oluwa
Kil' emi o fi fun?

Kini ngo fi fun Oluwa
Lat'inu okan mi
Ese ti ba gbogbo re je
Ko tile jamo nkan

Eyi l'ohun t'emi o se
F'ohun t'O se fun mi
Em'o mu ago igbala
Ngo kepe Oluwa

Eyi l'ope ti mo le da
Emi osi, are;
Em'o ma soro ebun 're
Ngo si ma bere si

Emi ko le sin b 'o ti to
Nko n'ise kan to pe
Sugbon e'mo sogo yi pe
Gbese ope mi po. Amin
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 11:02am On May 29, 2017
Fe enikeji re,
ase Oluwa ni
O sa f'ara Re s' apere
ni fi fe t'O fe wa.

Fe enikeji re
N'ire tabi n'ija
O ko wa pe k'a f'ota wa
k'a f'ore san uni

Fe enikeji re
Oluwa nke tantan
O ye ki gbogbo wa mura
Ka fenikeji we

Fe enikeji re
At'aladugbo 're
Pelu gbogb' eni yi o ka
At'ota re pelu

K'a f'enikeji wa
Bi Jesu ti fe wa
Jesu sa f'awon ota 're
O si sure fun won. Amin
Re: Yoruba Hymn by Ishilove: 9:19pm On May 29, 2017
You have a download link?
Re: Yoruba Hymn by Aaronsrod: 9:37pm On May 29, 2017
The Lord our God cannot be praised in this language! We must be humble and address the Almighty correctly in the English words that our sacrifice of Praise may be found worthy as we truly profess his Holy Name!

Take heed! Nahum 1:2
Re: Yoruba Hymn by Ishilove: 11:34pm On May 29, 2017
Aaronsrod:
The Lord our God cannot be praised in this language! We must be humble and address the Almighty correctly in the English words that our sacrifice of Praise may be found worthy as we truly profess his Holy Name!

Take heed! Nahum 1:2
Please tell me you're being sarcastic...
Re: Yoruba Hymn by TrajansKong: 7:53am On May 30, 2017
Ishilove:

Please tell me you're being sarcastic...
I don't know. But he seems to genuinely embody the inferiority complex that drives African Christians into a permanent moral and cultural wasteland and severe mental dysfunction. He seems like a normal Nigerian. undecided
Re: Yoruba Hymn by Ishilove: 8:51am On May 30, 2017
TrajansKong:

I don't know. But he seems to genuinely embody the inferiority complex that drives African Christians into a permanent moral and cultural wasteland and severe mental dysfunction. He seems like a normal Nigerian. undecided
.

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 3:18pm On Sep 20, 2018
Bi Osun gbe gbe etido
Tutu minimini
Bi igbo dudu eti omi
Ita na ipado
Bi igbo dudu eti omi
Itana ipado

Be lomo naa yio dagba
Ti nrin lona Baba
Tokan re fa si Olorun
Lati Igba ewe re
Tokan re fa si Olorun
Lati Igba ewe re
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:17am On Sep 25, 2018
Bi osun gbegbe eti do
Tutu minimini
Bi igbo dudu eti omi
B' Itanna ipado
Bi igbo dudu eti omi
Itana ipado

Be lomo naa yio dagba
Ti nrin lona Baba
Tokan re nfa si Olorun
Lati Igba ewe re
Tokan re nfa si Olorun
Lati Igba ewe re

Ewe tutu l'eba odo
B'o pe, a re danu
Be n'itanna ipa omi
Si are l'akoko re
Be n'itanna ipa omi
Si are l'akoko re

Ibukun ni fun omo na
Ti nrin l'ona Baba
Oba ti ki pa ipo da
Emi mimo lailai
Oba ti ki pa ipo da
Emi mimo lailai

Oluwa, 'Wo l'a gbekele
Fun wa l' ore-ofe
L'ewe, l’agba, ati n'iku
Pa wa mo b'omo Re
L'ewe, l’agba, ati n'iku
Pa wa mo b'omo Re
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:18am On Sep 25, 2018
Jesu onirele
Omo Olorun
Alanu Olufe
Gbo gbe omo Re

Fi ese wa ji wa
Si da wa nide
Do gbogbo orisa
Ti me lokan wa

Fun wa ni ominira
F'ife s'okan wa
Fa wa Jesu mimo
S'i bugbe l'oke

To wa l'ona ajo
Si je Ona wa
La okun aiye ja
S'imole orun

Jesu onirele
Omo Olorun
Alanu Olufe
Gbo gbe omo Re. Amin
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:01am On Sep 27, 2018
Jesu onirele
Omo Olorun
Alanu Olufe
Gbo gbe omo Re

Fi ese wa ji wa
Si da wa n'ide
Fo gbogbo orisa
Ti mbe lokan wa

Fun wa ni ominira
F'ife s'okan wa
Fa wa Jesu mimo
S'i bugbe l'oke

To wa l'ona ajo
Si je Ona wa
La okun aiye ja
S'imole orun

Jesu onirele
Omo Olorun
Alanu Olufe
Gbo gbe omo Re. Amin

1 Like

Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 9:20am On Mar 05, 2019
TAL'ENI naa ti n kan 'lekun okan mi(2ce)
Jesu Kristi Omo Olorun ni,
Silekun je' ko wole' lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Emi Mimo adaba orun ni,
Silekun je' ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olupese Oba awon Oba,
Silekun je ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olugbala Oba ayeraye,
Silekun je ko wole lo

Tal'eni naa ti n kan 'lekun
Okan mi? (2ce)
Olusegun alabo mi ni,
Silekun je ko wole lo
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:01am On Jul 07, 2021
Mo ti ni Jesu lore
O j'ohun gbogbo fun mi
Oun nikan larewa ti okan mi fe
Oun nitanna ipado
Oun ni Enikan naa
To le we mi nu kuro nin'ese mi
Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

Olutunu mi lo je ni gbogbo wahala
Oun ni ki n kaniyan mi l'Oun lori
Oun n'Itanna Ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

O gbe gbogbo banuje
At'irora mi ru
O j'Odi agbara mi n'gba danwo
Tori Re mo k'ohun gbogbo
Ti mo ti fe sile
O si f'agbara Re gbe okan mi ro
Bi aye tile ko mi
Ti Satan' dan mi wo
Jesu yoo mu mi d'opin irin mi
Oun n'Itanna ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe

Oun ki yo fi mi sile
Be ki yo ko mi nihin
Niwon ti m'ba figbagbo pofin Re mo
O jodi ina yi mi ka
N k'y'o beru-keru
Y'o fi manna Re bokan mi t'ebi npa
Gba m'ba dade n'ikehin
N o roju 'bukun Re
Ti adun Re y'o ma san titi lai
Oun n'Itanna ipado
Irawo Owuro
Oun nikan l'Arewa ti okan mi fe
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:02am On Jul 07, 2021
1. Eje k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju

2. On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju

3. O mbo gbogb’eda ‘laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju

4. O bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju

5. E je k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju. Amin.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:02am On Jul 07, 2021
A F’OPE F’OLORUN

1. A f’ope f’olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu eni t’araye nyo
‘gbat’a wa l’om’owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe.

2. Oba Onib’ore
Ma fi w asile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun

3. K’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo
Ti O ga julo lorun
Olorun kan laelae
T’aye at’orun mbo
Be l’o wa d’isiyi
Beni y’o wa laelae.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:03am On Jul 07, 2021
OKAN MI YIN OBA ORUN

OKAN MI YIN OBA ORUN

1. Okan mi yin Oba orun
Mu ore wa sodo re
‘Wo ta wosan, t’a dariji
Tal’aba ha yin bi Re ?
Yin Oluwa, yin Oluwa
Yin Oba ainipekun

2. Yin fun anu t’o ti fi han
F’awon Baba ‘nu ponju
Yin L Okan na ni titi
O lora lati binu
Yin Oluwa, yin Oluwa
Ologo n’u otito

3. Bi baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa
Jeje l’o ngbe wa lapa Re
O gba wa lowo ota
Yin Oluwa, yin Oluwa
Anu Re, yi aye ka

4. Angel, e jumo ba wa bo
Eyin nri lojukoju
Orun, Osupa, e wole
Ati gbogbo agbaye
E ba wa yin, e ba wa yin
Olorun Olotito. Amin.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:06am On Jul 07, 2021
KIIS' ONA T' O RORUN

1. Kiis' ona t' o rorun
Ni a nrin lo s'orun
Tor' opo egun l'o wa lona
Kiis 'ona t'o rorun
Sugbon Jesu pelu wa
Iwalaye Re fun wa l'ayo

ÈGBÈ:
Rara, kiis' ona t' o rorun/2x
Sugbon Jesu pelu mi
O ntan mole si mi
O si mu keru wuwo fuye

2. Kiis' ona t' o rorun
Idanwo ati iyonu
Pel' opo ewu l'a mba pade
Sugbon Jesu npa wa mo
K' ohunkohun ma se wa
O nto ona wiwo f' ese wa

3. Opo 'gba mo f'ese pa
T' o re mi ni ajo
Ti aniyan si nteri mi ba
Ojo kan to dara mbo
T' a o sinmi nile ogo
T' a o wa ni alafia titi
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:07am On Jul 07, 2021
KO SU WA LATI MA KO ORIN TI IGBANI
1. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani
Ogo f’olorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan
Ogo f’olorun, Aleluya!

Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo
Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re
Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
Ogo f’olorun, Aleluya!

2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada,
ogo f’olorun Aleluya!
Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun
Ogo f’olorun, Aleluya!

3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,
ogo f’olorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa Re
Ogo f’olorun, Aleluya!

4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa nde
Ogo f’olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist;
Ogo f’olorun, Aleluya!. Amin
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:08am On Jul 07, 2021
Aigbagbo bila! Temi l'Oluwa
Oun o si dide fun igbala mi,
Ki n sa ma gbadura, Oun o se 'ranwo:
'Gba Krist' wa lodo mi, ifoya ko si.

Bona mi ba su, Oun l'O sa n to mi,
Ki n sa gboran sa, Oun o si pese;
Biranlowo eda gbogbo ba saki,
Oro tenu Re so yo bori dandan.

Ife to n fi han, ko je ki n ro pe,
Yo fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si n ri lojojumo,
O n ki mi laya pe emi o la a ja.

Emi o se kun tori iponju,
Tabi irora? O ti so tele!
Mo moro Re pawon ajogun 'gbala,
Wo ko le sai koja larin wahala.

Eda ko le so kikoro ago
T'Olugbala mu kelese le ye;
Aye Re tile buru ju temi lo,
Jesu ha le jiya, kemi si ma sa.

Nje bohun gbogbo ti n sise ire,
Adun nikoro, ounje li oogun;
Boni tile koro, sa ko ni pe mo,
Gbana orin 'segun yio ti dun to!
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 4:10am On Jul 07, 2021
Mo'n te siwaju lona na
Mo'n goke si lojojumo
Mo n'gbadura bi mo nti lo
Oluwa jo gbe mi soke

Refrain:

Oluwa jo gbe mi soke
Fami lo si ibigiga
Apata to ga jumi lo
Oluwa Jo Gbe mi soke

Ife okan mi ko duro
Larin ‘yemeji at’eru
Awon miran le ma gbe’be
Ibi giga l’okan mi nfe.

Mo fe de ‘bi giga julo
Ninu Ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de ‘be
Ki nkorin lati’ibi giga.

Mo fe ki nga ju aye lo
Ninu Ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de ‘be
Oluwa mumi de ‘le na.

Fa mi lo si ibi giga
L’asi Te nko ni le de ‘be
Fa mi titi d’oke orun
Ki nkorin lat’ibi giga.
Re: Yoruba Hymn by obasolape(f): 5:39am On Jul 10, 2021
Igbagbo mi duro lori
Eje atododo Jesu
N'ko je gbekele ohun kan
Leyin oruko nla Jesu
Mo duro le Krist' apata
Ile miran, iyanrin ni

B'ire ije mi tile gun
Ore-ofe Re ko yi pada
Bo ti wu k'iji na le to
Idakoro mi ko ni ye
Mo duro le Krist' apata
Ile miran iyanrin ni

Majemu ati eje Re
L'emi o ro mo b'ikunmi de
Gbati ohun aye bo tan
O je ireti nla fun mi
Mo duro le Krist' apata
Ile miran iyanrin ni

Gbat'ipe kehin ba si dun
A! m ba le wa lodo Jesu
Ki nwo ododo Re nikan
Ki n duro niwaju ite
Mo duro le Krist' apata
Ile miran iyanrin ni My hope is built on nothing less
Than Jesus’ blood and righteous;
No merit of my own I claim
But wholly lean on Jesus’ name.
On Christ, the solid rock, I stand;
All other ground is sinking sand.

When darkness veils his lovely face,
I ret on his unchanging grace;
In every high and story gale
My anchor holds within the veil.
On Christ, the solid rock, I stand;
All other ground is sinking sand.

His oath, his covenant, his blood
Sustain me in the raging flood;
When all supports are washed away,
He then is all my hope and stay.
On Christ, the solid rock, I stand;
All other ground is sinking sand.

When he shall come with trumpet sound,
Oh, may I then in him be found,
Clothed in his righteousness alone,
Redeemed to stand before the throne!
On Christ, the solid rock, I stand;
All other ground is sinking sand.

(1) (Reply)

Buhari Congratulates Pastor Adeboye On His 80th Birthday / 1,300 Join Facebook Protest Over Pastor Ashimolowo's KICC Church / Question: "How Can I Live A Holy Life?"

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 56
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.