Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,256 members, 7,815,395 topics. Date: Thursday, 02 May 2024 at 11:44 AM

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! - Culture (9) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! (375810 Views)

If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here. Everybody Is Invited! / If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! / Do You Speak Yoruba? (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) ... (167) (Go Down)

Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by segoye2(m): 11:59pm On May 24, 2007
Odara la ti ma ko iwe ni ede wa, ati ojo ti mo bere si ni ko ede yoruba yi, mo tin gbona ninu ee daa daa, bee mi oti loo 5 minutes ri ni ile yoruba ni ayemi, but don't try me, nitori language student ni mi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 12:01am On May 25, 2007
kini gbogbo nti @richlaw type soke yen? iyalenu loje funmi wipe mi ole ka.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:02am On May 25, 2007
Penfold

A kii se babalawo ni idile ti wa o. Ewa ede ni mo karamasiki!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by segoye2(m): 12:03am On May 25, 2007
Babalawo, jeka soro ti ofe ba mi so yen lori msn , ibi ti obo ba wa, e mi a wa ri ni oni, e je ka loo sa, e ku ise agbara na
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 12:03am On May 25, 2007
now oye mi wayii.on pofo right? ebi e ko,aini se se lofa.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:04am On May 25, 2007
minute:

kini gbogbo nti @richlaw type soke yen? iyalenu loje funmi wipe mi ole ka.

grin grin grin grin O jo ti larubawa abi ti igbira, kaa leyo kookan yio ye o!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:06am On May 25, 2007
Segoye, awon eke babalawo bi i haywhy ko le yi , richylaw lo pada de o, ti iwo ba fe ba mi soro o le e pade mi lori oju iwe ayarabi asa ate ka iseabe@yahoo.com
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by NiteAngel(m): 12:07am On May 25, 2007
Richylaw,
Ki l'on mu ni Glasgow. Awon ogboju babalawo nwa e o.

E ranti lati ko awon omo yin ni ede yi o, bi be ko, ogun odun si igba ta wa yi be bere iru okun bayi e ni r'eiye,
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by segoye2(m): 12:10am On May 25, 2007
ha ha ahaha Mo san bu so sile ni shala shala, si oro si Nite Angel n so.

Babalawo tuntun, ese sir, bawo lese le ran mi lowo oooo, ani, e so fun mi sir. e sa mo ohun ti mo n wa, ki ni etu tu ooo?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:13am On May 25, 2007
minute:

now oye mi wayii.on pofo right? ebi e ko,aini se se lofa.

ki lode ti o wa n ri mi fin, igba  wo ni mo wa di alaini ise si o bayi? dakun je ki a fi ala si ori ile o. Gbogbo ni a ni ise, ayo ede la nyo ni bi o.
Nite Angel:

Richylaw,
Ki l'on mu ni Glasgow. Awon ogboju babalawo nwa e o.

E ranti lati ko awon omo yin ni ede yi o, bi be ko, ogun odun si igba ta wa yi be bere iru okun bayi e ni r'eiye,

Arabintin Angeli abiye fo  lowo ale
O didan ki omo temi gbo ede abinibi mi o. Glasgow ti mo wa yi, ise aje lo gbe omo re igberi okun o. O si didan kin kere dele. Ajo ki dun kodidere ma re Iwo, Odi dandan  ki aja o pada ja. Mo ja ewe mose awo ki n to wa o, nitorina won ko lee see ma a wa mi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:16am On May 25, 2007
segoye, emi ki ise babalawo titun, eniti o ti n se ogun re lati igba iwase wa ni o. Nje iwo ti se awon etutu ti mo ni ki o lo se ni aso rock , tabi iwaju ile iya charlie, tabi ile funfun ni amerika?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 12:18am On May 25, 2007
okay okay donot be pissed okay? mabinu o sogbo?
ayo ede len"yo? odun mi pe mio leso yoruba bio sen so yen,oju den timi pe ibadan nimotiwa,can u imagine?
omobadan ti yoruba odanmoran lenue?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:23am On May 25, 2007
minute:

okay okay donot be pissed okay? mabinu o sogbo?
ayo ede len"yo? odun mi pe mio leso yoruba bio sen so yen,oju den timi pe ibadan nimotiwa,can u imagine?
omobadan ti yoruba odanmoran lenue?

ha a Minute (iseju) ara ile ti wa ja o.Omo ibadan ni iya ti o bi mi lomo. (Ki oluwa ki o fi orun kee)
It's good you do appreciate your cultural heritage and indigenous source ride on babe.

ibadan mesi ogo
Ibadan maja maja
omo ajigun ja lehin olohun
omo afi kara hun fori mu
Oluyole , oloke kan obanta
oloke giriwo obanta

minute bi o ba n fe oluko ti o gbona jingiri ninu ede mo le e ma a ko o lori ero ayara bi asa o LOL
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by NiteAngel(m): 12:37am On May 25, 2007
Awo Richylaw,
Be ba so'lu Minute bo se gbona yi a jo rau rau. E ma ni lati f'omi la ni o, bi o je be ede ko le ma ko o
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 12:40am On May 25, 2007
lol. se omoye iseju tio gbami lati kaa nkan tio type yen shaa?

inu mi adun timo ba le ri eniti ama ko mi,tio bati ni si nkan mi leyin e, tori wipe erin e yen undecided undecided undecided

but mio bad sha? mon try right?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:43am On May 25, 2007
Nite Angel:

Awo Richylaw,
Be ba so'lu Minute bo se gbona yi a jo rau rau. E ma ni lati f'omi la ni o, bi o je be ede ko le ma ko o

Omo awo Angeli abiye fo owo alale
O ku u la a kaye , aye kan o ni ri o gbese o. Emi na ti n ro be e.


Egbo na eyin ara nairaland arakunrin ti o pe ara re ni SATAN ni oju ewe kerin ijiroro yi nko. Eru ba , o ti siyan la i duro gbobe. Omo ole grin grin grin grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 12:50am On May 25, 2007
minute:

lol. se omoye iseju tio gbami lati kaa nkan tio type yen shaa?

inu mi adun timo ba le ri eniti ama ko mi,tio bati ni si nkan mi leyin e, tori wipe erin e yen undecided undecided undecided

but mio bad sha? mon try right?


Omidan iseju, emi ki se adagba  ma la be o, mo mo wipe eru n ba o ni wipe ki babablawo ma da enu ife ko e grin, sugbon emi ko ni  ti igba kan bo ikan ninu o. Sebi ori ero ayara bi asa ni o ti ma gba eko,bawo  ni n kan miran se fe yo lehin re, eyi ma tun ko mi lomi nu o. O da mi loju wipe ti a ba n sunkun a ma riran sha. Bi o ba feran ede re ti o si fe ko si ko iwe simi lori  iseabe@yahoo.com
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 1:00am On May 25, 2007
eru tani onbami?

lord you are so good.

emiko ni ti igba kan bokan nini-
eyi matun kan mi lomi nu o,i love ur choice of words dude!

sofunmi ibo logbe dagba?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by NiteAngel(m): 1:07am On May 25, 2007
Gb'omo fo'mu, gb'omu fo'mo. Oju alejo lati je gbese ehin e lati san. A ni si lori ero ayara bi asa yen o, sugbon iroyin eko na a kan wa, Omo le'we ka'we e. Oluko gbiyanju koo ko daa daa. E maa ya'se
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by obonyunmi(f): 1:10am On May 25, 2007
ki le ri so o.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by minute(f): 1:20am On May 25, 2007
obo nyunmi? lol *sighs*
what a name!
i"d better run along now.
odabo o gbogbo eyin ara ile. smiley smiley smiley

hmmm@ richylaw, she ogbadun shaa?
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:24am On May 25, 2007
minute:

eru tani onbami?

lord you are so good.

emiko ni ti igba kan bokan nini-
eyi matun kan mi lomi nu o,i love your choice of words dude!

sofunmi ibo logbe dagba?
omidan iseju, awon agba bo won ni "ti han ti han o beyin, beyin ba se meji ,ko fo egungun ki o si funfun
Oju awo(plate) temi , lawo fi n gbobe.
A bi mi si orilede Naijira, mo si ka eko alakobere , girama ati iwe giga apakini ni orile ede naijiria. Ma je ki imo yoruba mi tan o je, awon obi mi mejeeji ko tile kawe ni orile ede naijiria rara , Ilu eko ni mo dagba si ni eti erekusu. Omo ajebota si ni awon kan a ma pe mi. Emi ti o si n ka oro mi yi ko le e ko ede yoruba tabi so daadaa titi ti mo fi bere girama , eyi ti ise F.G.C, Ilu oba ni mo si ti gba iwe eri eko giga apa keji ninu imo ise ayaworan ile ati agbekale re (architecture) . Nitorina ibi ti a gbe dagba ko ni yio fi ona ati gbo ede han.Mo fi da o loju wipe bi yoruba mi se ri ni ede oyinbo mi si ri pelu.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 1:36am On May 25, 2007
Minute
hmmm@ richylaw, she ogbadun shaa?

Mo wa pa, mo si duro digbidigbi. LOL
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by smile4kenn(m): 6:16am On May 25, 2007
Awon omo yoruba. Omo Uche ni mi. Mo ki ooooooh. Eku Nairaland.

Yoruba ni mo so ni asia. Mo ki OOOO


Omo nna
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 7:27am On May 25, 2007
Ekaro ninu ile yi oo!! E ee jire bi? Ejo e bami wa @richylaw lo o. Omo na gbona !! Amon enu agba ni obi ti ndun haun!! E so be fun !! E ni ko se iba fun agba ko to ma ba agba jeun oo. Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo.
Abi omo awo ni ise ni??
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by mishoo(m): 7:29am On May 25, 2007
smile4kenn:

Awon omo yoruba. Omo Uche ni mi. Mo ki ooooooh. Eku Nairaland.

Yoruba ni mo so ni asia. Mo ki OOOO


Omo nna
omo ibo, kaabo. Aje okuta ma mumi !! pele !1 se o fe kako e ni ede ni abi kilo wa wa oo cool cool cool
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by PrincessM(f): 8:58am On May 25, 2007
orisirisi!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by Nobody: 9:29am On May 25, 2007
orisirisi aborisirisi! Kini n kan gan an to n sele ni bi? se ka kan maa so yoruba to ba wa senu wa ni abi o ni nkan ti a n soro le lori? e laa yemi o,alejo ni mi.
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:31am On May 25, 2007
mishoo:

Ekaro ninu ile yi oo!! E ee jire bi? Ejo e bami wa @richylaw lo o. Omo na gbona !! Amon enu agba ni obi ti ndun haun!! E so be fun !! E ni ko se iba fun agba ko to ma ba agba jeun oo. Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo.
Abi omo awo ni ise ni??


Leekan si fun anfani ohun ti iwo fe ri.

Iba akoda o
iba aseda
iba origun mereerin agbaye
to fidi sole ti o ro.
Iba awon to tiwa ki n to ma be.
ewure ile o juba o di eran amuso
aguntan ile o juba , o di eran amusin
mo  juba eni iwaju loni o
e ma je ko hun mi.
ASE WA!

Alagba Mishoo,
E ku ojumo o ara o le bi?  Mo si ki yin lee kan si, si ori ijiroro yi. Mo fe ki e mo wipe ayaju si agba ki i to agba. E mi ki i se omo oodua ti ko mo eto (obligations) o. Awon agba ti fa mi mo ra, efo odu temi ki i si se aimo fun oloko. Emi ki i se ayaju si ara iwaju o. Mo ti fi owo fun awon agba, won ko mi bi a se n fowo , mo fowo mi mo tan ni mo ba ta kete ti mo si n ba agba je o.
(Awon ofo to pa si oju iwe keje yen ti po ju ojo ori re lo) Nje e ti le mo  ojo ori mi ni,
Mo fe ki e mo wipe ojo ori ko lagba rara , a tete de be si ko ni atete dara fun o.Eni to ba yara logun gbe.
Laise ani ani o dabi eni wipe mo ti yan na na gbogbo ikilo tabi ibeere yin fun yin. Bi e ba si tunn pada sehin die lati ka gbogbo oun ti mo ti ko sehin ninu okun ijiroro yi , e o ri daju wipe ko si oro iyaju kankan, tabi isokuso , tabi oro alufansa o, eyin ni ki e kago ki e to wo ile o .

Nitorina mo ti di eegun  ile loni o
Emi ki i se eni a  n gba loju
Mo ti di  afin ile loni , emi ki i se eni an ti laya,
Arigini aringini , aringinigini woja loruko a n pe, grin grin grin

Do not be afraid , our God is real
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by richylaw(m): 9:40am On May 25, 2007
Posted by: candy  

orisirisi aborisirisi! Kini n kan gan an to n sele ni bi? se ka kan maa so yoruba to ba wa senu wa ni abi o ni nkan ti a n soro le lori? e laa yemi o,alejo ni mi.  



Arabinrin Adun (Candy)

Bi awon akegbe mi yio ba gbami laaye lati je agbenuso lori okun ijiroro yi,     Mo fe fi asiko yi kiyin  ku abo si ori eto  o. Ewa ede ati asa ibile wa ni ohun ti a ngbe laruge ni ogbun okun ijiroro ti eleyi. Bi o ti le je wipe opo ti ko "orisirisi" gege bii iwo na ti se ri,sugbon emi yio fe ki o mo wipe gbogbo edo fini ohun gbogbo ti o n sele ni duniyan ni a le jiroro ni pa re ni ibi yi. O bere lati ori ere idaraya, irohin , Oselu, imoran fun loko laya ni ede abinibi wa ati bebe lo.E tu ra ka lati da si oro na  If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here!
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by ronnieslimz(f): 11:09am On May 25, 2007
nigbawo ni e bere thread yi ti emi omo nipa re sugbon sa ohun gbogbo nsisefun rere. . eku ile eyin omo ile karo ojire, esi ku dede iwoyi oo. . se dada nimo bayin? grin grin
Re: If You Can Speak Yoruba, Talk It In Here! by haywhy(m): 11:22am On May 25, 2007
Richy law, mo n gbadun awon ikaramasiki to lamilaaka ti o se si oke yen, Ko ni bu o lapa ooooooo! Yoo si ma ju oo se!

Richy law ooooooo
Itun lo ni ki won fi oun rere tun e she
Ifa loni ki won fi oun rere fa e wo
Abeere loni ki won fi oun rere beere re wo
Tigi tope ni ishe anu afomo
Omo araye o ma she anu ee
Awon araye aje ki ori tire she oooo

(1) (2) (3) ... (6) (7) (8) (9) (10) (11) (12) ... (167)

Modern Traditional Attire Of Nigeria / Pictures Of Nigeria Traditional Attire / Igbo Names & Their Meanings

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 47
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.