Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,156,841 members, 7,831,721 topics. Date: Saturday, 18 May 2024 at 04:01 AM

Share Your Best Hymns - Religion (12) - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Share Your Best Hymns (41964 Views)

Post Your Favourite Christian Hymns / I Need Deeper Life Bible -gospel Hymns CD / Post Yoruba Christian Hymns Here (2) (3) (4)

(1) (2) (3) ... (9) (10) (11) (12) (13) (Reply) (Go Down)

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:09am On Oct 26, 2022
C.M.S. 563, S.O. ED D7s (FE 135) "Iwo ki ise eru mo, Iwo di arole Olorun nipase Kristi" - Gal. 4:7

1. EWE ti Oba orun,
Korin didun be ti nlo
Korin ‘yin Olugbala
Ologo ‘nu ise Re.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi
Ayo won l'awa o ri.

2. A nlo sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi,
Ayo won l'awa o ri.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

3. Korin agbo kekere
E o simi n'ite Re, ‘
Bit'a pese 'joko nyin
Ibe si n'ijoba nyin.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

4. W'Oke, omo imole
Ilu Sion wa lokan
Ibe n‘ile wa titi;
Ibe l'ao r'Oluwa.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

5. Kerubu, tesiwaju
Serafu, ma jafara
Kristi Omo Baba nwi
Pe laifoiya ka ma lo.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

6. Jesu, a nlo l'ase Re,
A ko‘hun gbogbo sile
lwo ma j‘ amona wa,
A o si ma ba o lo.

Egbe: A nlo ‘le sodo...

7. A f’ogo fun Baba wa,
A f'ogo fun Omo Re;
Ogo ni f’Emi Mimo,
Mu wa de ‘le ayo na.

Egbe: A nlo ‘le sodo Olorun
Lona t'awon Baba rin
Nwon si nyo: nisisiyi
Ayo won l'awa o ri. Amen

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:27am On Oct 26, 2022
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin
Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na
Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide
Jesu lo nto mi lo, isegun daju
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 2
Ninu ise isin mi, b’okunkun basu
Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole
Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada
Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi.
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 3
Bi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re, Yio Mole simi
Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke
Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 4.
Nigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju, labe apa re
Y’o ma f’owo re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f’e to.
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:32am On Oct 28, 2022
OGO NI F'ORUKỌ OLUWA

1. Jesu ala-bu-kun a-wa yin ọ
A kò kiki 'fẹ́ oore rẹ
Alagbara, ẹni mímọ
Ogo nla ni f'orukọ rẹ

Chrs..
Óòoo...........ogo. Óòoo.........ogo
Ogo ni f'orukọ~Oluwa
Óòoo...........ogo. Óòoo.........ogo
Ogo ni f'orukọ rẹ

2. Olurapada nla, oluwa wa
Imọlẹ ọjọ ~ayeraye
Jẹ k'awọn mimọ ni gbogbo aye
Kọrin iyin ailopin rẹ

3. Lat'ori itẹ ogo ti ọ́run
S'ori agbelebu itiju
E'n tó kù, to ra wa pada
Ki ẹlẹṣe ba tun le ye

4. Sọkalẹ wa, ọba àìkú
Wa gba' jọba ogo re
Wa ma jọ́ba, titi lailai
Ki gbogbo 'jọba jẹ tirẹ

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 12:43am On Nov 01, 2022
Blessed Assurance

Oda mi loju, mo ni Jesu!
Itowo adun oorun l’eyi je!
Mo di ajogun igbala nla,
Eje Re we mi, a tun mi bi.

Egbe:
Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi;
Ngo so itan na, ngo korin na,
Ngo yin Olugbala mi titi.

Ngo teriba fun tayotayo,
Mo le ri iran ogo bibo Re;
Angeli nmu ihin didun wa
Ti ife at’anu Re si mi.

Egbe:

Ngo teriba fun, ngo simi le
Mo di ti Jesu, Mo d’eni ’bukun,
Ngo ma sora, ngo si gbadura,
Ki ore Re ma fi mi sile.

Egbe:

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:05pm On Nov 01, 2022
ONIBU ORE HYMN LYRICS

Verse 1
Oluwa orun on aye
Wo Niyin atope ye fun
Bawo la ba ti fe o to
Onibu ore

Verse 2
Orun ti nran atefefe
Gbogbo eweko nso fe re
Wo lo nmu irugbin dara
Onibu ore

Verse 3
Fun ara lile wa gbogbo
fun gbogbo ibukun aye
Awa yin o, a si dupe
a onibu ore

Verse 4
O ko du wa li omo re
o fi fun aye ese wa
o si f'ebun gbogbo pelu
onibu ore

Verse 5
O fun wa l'Eni Mimo re
Emi iye atagbara
O rojo ekun ibukun re
Le wa lori

Verse 6
Fun idariji ese wa,
ati fun ireti orun
Ki lohun ta fin fun o
O je isura ti taye
Onibu ore

Verse 7
Owo ti anna, ofo ni
Sugbon eyi tafin fun o
O je isura ti taye
Onibu ore

Verse 8
Ohun ta bun o Oluwa
Wo o an le pada fun wa
Layo la ta o lore
Onibu ore

Verse 9
Ni odo re lati san wa
olorun olodumare
Je ka le ba O gbe titi
Onibu ore
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:40pm On Jan 26, 2023
1. Mo nduro lori ileri Krist' Oba
Eniti a o ma yin titi laelae
Ogo f‘Olorun, emi yo ma korin
Mo nduro lori ileri Re.

Emi nduro......
(Mo nduro de ‘leri, Mo nduro de ‘leri)
Emi nduro lori ileri Oluwa
Emi nduro......
(Mo nduro de ‘leri, Mo nduro de ‘leri)
Emi nduro lori ileri Re.

2. Mo nduro le ileri ti ko le ye
Gbati iji 'yemeji at‘ eru ba de
Nipa Oro Re li emi yo segun
Mo nduro lori ileri Re,

3. Ileri Re la mi loju lati ri
Iwenumo pipe ninu eje Re
Ileri Re so okan mi d‘om'nira
Mo nduro lori ileri Re.

4. Mo nduro le ileri Krist' Oluwa
Ife lo fi so mi po mo ara Re
Nipa oro Re mo nsegun lojojo
Mo nduro lori ileri Re
Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:53am On Feb 25, 2023
B’o ti dun lati gba Jesu

Bi iwo ba gbagbo, iwo o ri ogo Olorun. Jn. 11:40

1. B’o ti dun lati gba Jesu
Gbo gegebi oro Re;
K’a simi lor’ ileri Re,
Sa gbagbo l’Oluwa wi

Jesu, Jesu, emi gbagbo,
Mo gbekele n’gbagbogbo,
Jesu, Jesu, Alabukun
Ki nle gbekele O si.

2. B’o ti dun lati gba Jesu,
K’a gb’eje ‘wenumo Re
Igbagbo ni ki a fi bo
Sin ‘eje wenumo na.

3. B’o ti dun lati gba Jesu,
Ki nk’ara ese sile,
Ki ngb’ayo, iye, isimi
Lati odo Jesu mi.

4. Mo yo mo gbeke mi le O,
Jesu mi, Alabukun;
Mo mo pe O wa pelu mi,
Ntoju mi titi dopin.
Amin.

Tis so sweet to trust in Jesus

If thou wouldest believe, thou shouldest see the glory of God. John.11:40

1. 'Tis so sweet to trust in Jesus,
Just to take Him at His word:
Just to rest upon His promise:
Just to know, 'Thus saith the Lord.

Jesus, Jesus, how I trust Him!
How I've proved Him o'er and o'er
Jesus, Jesus, precious Jesus!
O for grace to trust Him more!

2. O how sweet to trust in Jesus,
Just to trust His cleansing blood;
Just in simple faith to plunge me
'Neath the healing, cleansing flood!

3. Yes, ‘tis sweet to trust in Jesus,
Just from sin and self to cease;
Just from Jesus simply taking
Life and rest, and joy and peace.

4. I'm so glad I learn'd to trust Thee
Precious Jesus, Saviour, Friend;
And I know that Thou art with me,
Wilt be with me to the end.

Amen.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:58am On Feb 25, 2023
Nigba igbi aiye ba dide si o,
T' okan re baje pe gbogbo nkan segbe,
Siro ibukun re, ka won lokokan,
Enu y'o ya o fun nkan t' Oluwa t'se.

Refrain
Ro 'bukun re ka won lokokan,
Ro ohun t' Olorun se fun o;
Ro 'bukun re, ka won lokokan,
Ro 'bukun re, ri nkan t' Olorun ti se.

Eru aniyan ha ti n pa okan re?
Agbelebu ti 'wo nru ha si wuwo?
Siro ibukun re le 'yemeji lo,
Iwo y'o si korin b' ojo ti nkoja.

Nigbat' ini elomi kun o loju,
Ranti Krist n 'oro aimoye fun o,
Siro ibukun re t' owo ko le ra,
At' ere re lorun, ile re l' oke

Beni larin ija b' o ti wu ko ri,
Mase ba okan je mo p' Olorun mbe,
Siro ibukun re, Angeli y'o wa,
Fun ranwo on 'tunu d'opin ajo re.

Source: YBH #658

When upon life’s billows you are tempest tossed,
When you are discouraged, thinking all is lost,
Count your many blessings name them one by one,
And it will surprise you what the Lord hath done.

Refrain:

Count your blessings, name them one by one;
Count your blessings, see what God hath done;
Count your blessings, name them one by one,
And it will surprise you what the Lord hath done.

Are you ever burdened with a load of care?
Does the cross seem heavy you are called to bear?
Count your many blessings, every doubt will fly,
And you will be singing as the days go by.

When you look at others with their lands and gold,
Think that Christ has promised you His wealth untold.
Count your many blessings, money cannot buy
Your reward in heaven, nor your Lord on high.

So amid the conflict, whether great or small,
Do not be discouraged, God is over all;
Count your many blessings, angels will attend,
Help and comfort give you to your journey’s end.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:34pm On Mar 02, 2023
11. Recessional Hymn Akokun 22 “B’o ba ni Jesu k’o dimu”

B’o ba ni Jesu k’o dimu,
K’o si toro imuduro,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.
Mu mi duro, mu mi duro,
Mu mi duro dopin,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Ninu ofi-ola aiye,
Pelu danwo arotele,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba ‘banuje ile
B’a d’ori okan mi kodo;
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba wahal’ aiye l’otun
Idanwo Esu li osi,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba Esu gbe mi soke,
T’o fe k’emi k’o teriba,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigbat’ o ku emi nikan,
Ti ko si alabaro mo;
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:56am On Mar 11, 2023
1 Nigbati ‘gbi aye yi ba nyi lu o,
To si dabi enipe gbogbo re pin,
Ka ibukun re, siro won l‘okokan,
Ise Oluwa yo je ‘yanu fun o

Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan,
Ka ‘bukun re, wo ‘se Olorun;
Ka ‘bukun re, ka won l‘okokan,
Ka ‘bukun re, wa ri ‘se t‘Olorun se.

Eru aniyan ha nwo ‘kan re l‘orun!
Ise t‘a pe o si ha soro fun O;
Ka ‘bukun re, ‘yemeji yo si fo lo,
Orin iyin ni yo si gb‘enu re kan.

3 ‘Gbat‘ o ba nwo awon oloro aye,
Ronu oro ti Jesu ti se leri;
Ka ibukun re, owo ko le ra won,
Ere re l‘orun ati ‘le re l‘oke.

4 Ninu gbogbo ayidayida aye,
Mase foya, Olorun tobi julo;
Ka ‘bukun re, awon angel‘ yo to o
Won yo si ran o lowo titi d‘opin.
Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:48pm On Mar 20, 2023
11. Recessional Hymn Akokun 22 “B’o ba ni Jesu k’o dimu”

B’o ba ni Jesu k’o dimu,
K’o si toro imuduro,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.
Mu mi duro, mu mi duro,
Mu mi duro dopin,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Ninu ofi-ola aiye,
Pelu danwo arotele,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba ‘banuje ile
B’a d’ori okan mi kodo;
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba wahal’ aiye l’otun
Idanwo Esu li osi,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigba Esu gbe mi soke,
T’o fe k’emi k’o teriba,
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.

Nigbat’ o ku emi nikan,
Ti ko si alabaro mo;
Jesu, Oluwa mi,
Mu mi duro dopin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:13pm On Mar 22, 2023
Ninu irin ajo mi, beni mo nkorin
Mo n toka si kalfari, N’ibi eje na
Idanwo lode ninu, l’ota gbe dide
Jesu lo nto mi lo, isegun daju
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 2
Ninu ise isin mi, b’okunkun basu
Un o tubo sunmo Jesu, y’o tan imole
Esu le gb’ogun ti mi, kin le sa pada
Jesu lo nto mi lo, ko se’wu fun mi.
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 3
Bi mo tile bo sinu afonifoji
Imole itoni Re, Yio Mole simi
Yio na owo re simi, Yio gbe mi soke
Un o ma tesiwaju, b’o ti nto mi lo
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Stanza 4.
Nigbati iji aye yi ba yi lu mi
Mo ni abo t’o daju, labe apa re
Y’o ma f’owo re to mi titi de opin
Ore ododo ni, A! mo ti f’e to.
Egbe:
A! mo fe ri Jesu kin ma w’oju re,
Ki nma korin titi nipa ore re
Ni ilu ogo ni ki ngbohun soke
Pe mo bo, ija tan, mo de ile mi.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 8:55pm On Mar 27, 2023
Bi Krist ti da okan mi nde
Aye mi ti dabi orun
Larin 'banuje at' aro
Ayo ni lati mo jesu

Chorus:
Halleluya Ayo l'o je
Pe mo ti ri 'dariji gba
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s'ewu Jesu wa nibe

Mo ti ro pe orun jinna
Sugbon nigba ti Jesu de
L'orun ti de 'nu okan mi
Nibe ni yo'o si wa titi

Nibo l'a ko le gbe l'aiye
L'or'oke tabi petele
L'ahere tabi agbala
Ko s'ewu Jesu wa nibe
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:24am On Mar 28, 2023
1. GBO-GB’ ogo iyin ola,
Fun O oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
‘Wo l’ Oba Israeli,
Om’ Alade Dafidi,
T’ O wa l’ Oko Oluwa,
Oba olubukun.
Gbogb’ ogo iyin ola
Fun O, Oludande,
S’ Eni t’ awon omode
Ko Hosanna didun!
2. Egbe awon maleka,
Nyin O l’ oke giga;
Awa at’ eda gbogbo
Si dapo gberin na.
3. Awon Hebru lo, saju,
Pelu imo ope,
Iyin, adura, at’ orin,
L’ a mu wa ‘waju Re.
4. Si O saju iya Re,
Nwon korin iyin won;
‘Wo t’a gbega nisiyi,
L’ a nkorin iyin si.
5. ‘Wo gba orin iyin won:
Gb’ adura t’a mu wa,
‘Wo ti nyo s’ ohun rere,
Oba wa Olore.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:43am On Apr 08, 2023
1. Jesu mimo Ore airi
Oluranlowo alaini
N'nu ayida aiye, ko mi
K'emi le romo O.

2.Ki nsa n‘idapo mimo yi,
Gba ohun t‘O fe ugo kun bi?
B‘okan mi b‘eka ajara
Ba sa le ro mo O.

3. Are ti m'okan mi pupo
Sugbon o wa r'ibi simi
T'ori t'o room O

4. B'aiye d'ofo mo mi loju
Ba gba ore at'ara lo
Ni Suri ati laibohun
L'emi o romo O

5 ‘Gba t‘o k‘emi nikan soso,
Larin idamu aye yi,
Mo gb‘ohun ife jeje na
Wipe, “Sa ro mo Mi

6 B‘are ba fe mu igbagbo,
T‘ireti ba si fe saki,
Ko si ewu fun okan na
Ti o ba ro mo O.

7 Won ko beru ‘rumi aye
Nitori ‘Wo wa nitosi;
Won ko si gbon b‘iku ba de
‘Tori won ro mo O.

8 Ire sa ni l‘ohun gbogbo,
Ko s‘eni le daya fo mi
‘Gba mo fi O s‘Olugbala,
Ti mo si ro mo O.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 1:19pm On Apr 17, 2023
TOLUWA NILE ATEKUN RE

T'Oluwa Nile at'ekun re
Aye at'ekun 'nu re
O fi idi re sole lor'okun
At I lori isan omi

Egbe
Gbe ori yin soke, eyin ilekun
Ka gbe yin soke
K'Oba Ogo wole wa

Tani yo gori oke yi lo?
Ori oke Oluwa
Tani yo duro niwaju Re?
Niwaju Oluwa wa

Eni ti o ni owo mimo
To so ni aya funfun
Ti ko gb' okan re soke s'asan
Ti ko si bura etan

Awa ni iran ti nsaferi Re
Saferi Re Oluwa
Awa yo si ri ibukun gba
Lowo Olorun Jakob

A! Tani Oba awon oba
Ti'se Oba Ogo yi?
Oluwa awon omo Ogun
Oun naa l'Oba ogo

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:42am On Apr 18, 2023
1. Bukun 'le wa at'ebi wa, at'ara wa/2ce
Ibukun orun, iranwo, Re,
Ibukun orun ko fi kari awa,
K'O fi fun wa o, l'aye l'orun o,
Baba orun

2. Tu wa lara, Alagbara, se 'toju wa/2ce
Itunu Re, alafia Re,
Ike Re, K'O fi toju wa, ye,
Awa mbe O o, gbo adura wa,
Oba Ogo.

3. Baba fun wa l'Emi mimo at'agbara/2ce
Iranse orun, ebun lat'orun
Itunu Baba, k'o wonu okan wa,
K'o gbe 'nu wa o, k'o fun wa l'ayo,
Oba Orun.

4. Awa f'iyin at'ope fun Baba l'orun/2ce
Iyin fun 'ranwo, ope fun anu,
Ayo fun 'dasi ti a nri lojojo,
Ope fun O o, a tun juba Re,
Baba awa.
Amin

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:55pm On Nov 13, 2023
SOFTLY AND TENDERLY (In Yoruba)

Gbo bi Oluwa ti npe lohun jeje
O nkesi o, at 'emi
Wo! O nfi suru duro lenu ona
Nduro de t'emi tire

ÈGBÈ:
Wa 'le... wa 'le....
Enyin t'are mu, wa le
Tifetife li Olugbala nkigbe
O npe elese wa 'le

DOH is A flat
m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -||
d :d :d :m : - .r :d |r : - : - : - : - : -||
m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -||
d :d :f :m : - .d :r |d : - : - : - : -||
REFRAIN
s, |r : - : - : - : - :m |d : - :r :m : - : -||
r :r :r :m.m : - :fe |s : - :fe :f : - : -||
m : - .r :d :d :t, :d |r :d :l, :l, :s, : -||
d.d : - :f :m.d : - :r |d : - : - : - : -||
(Copied).
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 3:56pm On Nov 13, 2023
CCC. HYMN 575
1.Oluwa mafi mi se gbagbe
Ranti mi toba de'joba Re
Nibi igbala ohun ayo gbe wa
Nibi igbala ayeraye

2 Oluwa to loke to nile
Ohun lolorun to laye
Bo tiwu kile aiye dun to
A o faye sile nigbakan.

3 Nigba Maria bi Jesu
Awon amoye wa
Gbogbo won foribale fun
Won si tun ta jesu loore. Amin.
Re: Share Your Best Hymns by Blackman101: 4:34pm On Nov 13, 2023
We have heard the joyful sound:
Jesus saves! Jesus saves!
Spread the tidings all around:
Jesus saves! Jesus saves!
Bear the news to every land,
Climb the steeps and cross the waves;
Onward!—’tis our Lord’s command;
Jesus saves! Jesus saves!
2
Waft it on the rolling tide,
Jesus saves, Jesus saves;
Tell to sinners far and wide,
Jesus saves, Jesus saves;
Sing, ye islands of the sea,
Echo back, ye ocean caves;
Earth shall keep her jubilee,
Jesus saves, Jesus saves.
3
Sing above the battle’s strife,
Jesus saves, Jesus saves;
By His death and endless life,
Jesus saves, Jesus saves;
Sing it softly thru the gloom,
When the heart for mercy craves,
Sing in triumph o’er the tomb,
Jesus saves, Jesus saves.
4
Give the winds a mighty voice,
Jesus saves, Jesus saves;
Let the nations now rejoice.
Jesus saves, Jesus saves;
Shout salvation full and free,
Highest hills and deepest caves,
This our song of victory,
Jesus saves, Jesus saves.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 2:58am On Nov 16, 2023
SI O OLUTUNU ORUN

1. Si o Olutunu Orun
Fun ore at’agbara Re
A nko, Aleluya

2. Si O, ife eni t’Owa
Ninu Majemu Olorun
A nko, Aleluya

3. Si O agbara Eni ti
O nwe ni mo, t’o nwo ni san
A nko, Aleluya

4. Si O, Oluko at’ore
Amona wa toto d’opin
A nko, Aleluya.

5. Si O, Eniti Kristi ran
Ade on gbogbo ebun re
A nko, Aleluya. Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:54am On Nov 19, 2023
CCC. HYMN 575
1.Oluwa mafi mi se gbagbe
Ranti mi toba de'joba Re
Nibi igbala ohun ayo gbe wa
Nibi igbala ayeraye

2 Oluwa to loke to nile
Ohun lolorun to laye
Bo tiwu kile aiye dun to
A o faye sile nigbakan.

3 Nigba Maria bi Jesu
Awon amoye wa
Gbogbo won foribale fun
Won si tun ta jesu loore. Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:55am On Nov 21, 2023
Oluwa ran mi ni’se, Aleluya!
Iwọ ni un o jẹ iṣẹ na fún;
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.


A rán mi ni’se ayọ, Aleluya!
Un ọ j’iṣẹ na fún ọ ọrẹ mi;
Iṣẹ lat’oke wa ni Aleluyah!
Jésù sọ, mo mọ pé otọ ni.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.


A n’ọwọ iye sí ọ, Aleluya!
Ao fi’ye ailopin fún ọ;
T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
Wòó, On nìkan l’o le gbala.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 5:56am On Nov 21, 2023
OLORI IJO T'ORUN

Olori ijo t' orun,
L' ayo l' a wole fun O;
K' o to de, ijo t' aiye,
Y'o ma korin bi t' orun,
A gbe okan wa s' oke,
N' ireti t' o n' ibukun;
Awa kigbe, awa f' iyin
F' Olorun igbala wa.

Bi a wa ninu 'ponju,
T' a nkoja ninu ina,
Orin ife l' awa o ko.
Ti o mu wa sunmo O;
Awa sape, a si yo,
Ninu ojurere Re
Ile t' o so wa di Tire,
Y'o pa wa mo titi lai.

Iwo mu awon enia Re
Koja isan idanwo;
A ki o beru wahala,
'Tori O wa nitosi,
Aiye, ese at' Esu,
Kojuja si wa lasan,
L' agbara Re, a o segun,
A o si ko 'rin Mose.

Awa f' igbagbo r' ogo,
T' O nfe lati fi wa si,
A kegan ere aiye,
Ti a fi siwaju wa,
Bi O ba si ka wa ye,
Awa pelu Stefen t'o ku
Y'o ri O bi o ti duro
Lati pe wa lo s' orun.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:00am On Nov 21, 2023
FUN MI NI IWA PELE

Fun mi n' iwa pele,
Okan tutu;
Ifarabale bi
T' Oluwa mi;
Irele on suru
At' opo oiyonu,
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

Fun mi n' itelorun
N' ipo k' ipo;
Ko le re 'le ju yi
T' a bi Jesu.
Fun mi n' itunu Re.
At'iranlowo Re
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

Fun mi ni itara
S' ipa Tire;
Aniyan at' ife
S' ohun t' orun;
Fun mi n' iwa mimo,
Ikorira ese,
Ninu ohun gbogbo
Ki njo Jesu.

Fun mi ni igbagbo
At' ireti;
Fun mi l' ayo 'gbala
Ninu Jesu;
F' emi iye fun mi,
Fun mi l' ade ogo,
'Gbati mo ba jinde
Ki njo Jesu.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 6:47am On Nov 21, 2023
Oluwa ran mi ni’se, Aleluya!
Iwọ ni un o jẹ iṣẹ na fún;
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.


A rán mi ni’se ayọ, Aleluya!
Un ọ j’iṣẹ na fún ọ ọrẹ mi;
Iṣẹ lat’oke wa ni Aleluyah!
Jésù sọ, mo mọ pé otọ ni.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.


A n’ọwọ iye sí ọ, Aleluya!
Ao fi’ye ailopin fún ọ;
T’o ba wo Jesu nikan, Aleluya!
Wòó, On nìkan l’o le gbala.

Egbe:
Wo k’o ye, Arakurin
Wo Jesu ki o sí ye
A kọ sínú ọrọ Rẹ, Aleluya!
P’ẹni t’o ba wo Jesu y’o ye.

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 9:14pm On Nov 26, 2023
AO sise ! ao sise! Om’ -Olorun ni wa,
Jek’ a tele ona ti Oluwa wa to;
K’ a f’ imoran Re so agbara wa d’ otun,
K’ a fi gbogbo okun wa sise t’ a o se.

Egbe:
Foriti ! Foriti !
Foriti ! Foriti !
K’ a reti, k’ a s’ ona
Titi Oluwa yio fi de.

Ao sise ! ao sise ! bo awon t’ ebi npa,
Ko awon alare lo s’ orisun iye !
Ninu agbalebu l’ awa o ma s’ ogo,
Nigbat’ a ba nkede pe, ” Ofe n’ igbala,”

Egbe:

Ao sise ! ao sise ! gbogbo wa ni yio se,
Ijoba okunkun at’iro yio fo,
Ao si gbe oruko Jehofah leke, won,
Ninu orin iyin wa pe, “Ofe n’ igbala,”

Egbe:

Ao sise ! ao sise ! I’ agbara Oluwa,
Agbada at’ ade yio si je ere wa;
Ile awon oloto yio si je ti wa,
Gbogbo wa o jo ho pe, “Ofe n’ igbala,”

Egbe:

Amin.

1 Like

Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:55am On Nov 30, 2023
1. BABA to da orun meje
Ati ‘le meje pelu
Aiye lo se ekedogun
lyin ni f’oruko Re.

Egbe: Ijinle loro na
Awamaridi si ni,
Ijinle loro na
Awamaridi si ni.

2. Orun, Osupa, Irawo
Awon ni ‘mole aiye
Okuta Oniyebiye
Awon ni ‘mole ‘sale.

Egbe: Ijinle loro na...

3. Abo Oluwa Onike
L’awa Egbe bora mo
Ko s‘ohun ‘bi to le se wa
Lagbara Metalokan.

Egbe: Ijinle loro na...

4. Eni loyun a bimo la
Agan a t’owo b‘osun
Olomo ko ni padanu
Iku ko ri wa gbe se.

Egbe: Ijinle loro na...

5. Ko s’eniti nri ‘di okun
A ki nri ‘di olosa
Baba to da orun on aiye
Ma je k’aiye r’idi mi.

Egbe: Ijinle loro na...

6. Awon Agbara Emi meje
Ta fi wo HOLY MICHAEL
To si fi segun Lusifa
Lojo ogun Olorun.

Egbe: Ijinle loro na...

7. Baba, Omo, Emi Mimo
Metalokan to gunwa
Jowo ko gbo adura wa,
Larin Egbe Serafu.

Egbe: Ijinle loro na
Awamaridi si ni,
Ijinle loro na
Awamaridi si ni. Amin
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 11:27am On Mar 15
BI mo ti ri – laisawawi,
Sugbon nitori eje Re,
B’O si ti pe mi pe ki nwa –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri – laiduro pe,
Mo fe k’okan mi mo toto,
Sodo Re t’o le we mi mo.
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu;
Eru l’ode, eru ninu –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -osi, are,
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri -‘wo o gba mi,
‘wo o gba mi t’owo t’ese
‘Tori mo gba ‘leri Re gbo –
Olugbala, mo de.

Bi mo ti ri – ife Tire
L’ o sele mi patapata;
Mo di Tire, Tire nikan –
Olugbala, mo de.

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:30am On Mar 17
Jesu, a fe pade,
Lojo Re mimo yi;
A si yite Re ka,
Lojo Re mimo yi:
'Wo Ore wa orun,
Adura wa n bo wa,
Boju wo emi wa
Lojo Re mimo yi.

A ko gbodo lora,
Lojo Re mimo yi
Li eru a kunle
Lojo Re mimo yi;
Ma taro ise wa,
K'Iwo ko si ko wa,
Ka sin O bo ti ye
Lojo Re mimo yi

A teti soro Re
Lojo Re mimo yi;
Bukun oro ta gbo,
Lojo Re mimo yi;
Ba wa lo 'gbat'a lo,
Fore igbala Re
Si aya wa gbogbo,
Lojo Re mimo yi.

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 22
Are mu O, okan re poruru?
So o fun Jesu:
Ibanuje dipo ayo fun o?
So o fun Jesu nikan.

Egbe:
So o fun Jesu; so o fun Jesu
Oun lore ti yoo mo
Ko tun sore
Ati'yekan bi Re
So o fun Jesu nikan

Asun-dakun omije lo nsun bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu,
O l'ese to farasin f'eniyan
So o fun Jesu nikan

Egbe:

'Banuje teri okan re ba bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
O ha nsaniyan ojo ola bi?
So o fun Jesu nikan

Egbe:

Ironu iku mu o damu bi?
So o fun Jesu, so o fun Jesu
Okan re nfe ijoba Jesu bi!
So o fun Jesu nikan

Egbe:

Amin.
Re: Share Your Best Hymns by obasolape(f): 4:24am On Mar 24
Hosanna s'omo Dafidi
Hosanna, e korin
Olubukun l'Eniti mbo
L'oruko Oluwa.

Hosanna s'omo Dafidi
L'egbe Angeli nke
Gbogbo eda jumo gberin
Hosanna s'Oba wa

Hosanna awon Heberu
Ja imo ope s'ona
Hosanna e mu ebun wa
Fi tun ona Re se.

T'agba t'ewe nke Hosanna
Ki ijiya Re to de
Loni a si nko Hosanna
B'O ti njoba loke

B'O ti gba'yin won nigbanaa
Jo gba ebe wa yi
Lorun k'a le ba Angeli korin
Hosanna s'Oba wa.

Amin.

(1) (2) (3) ... (9) (10) (11) (12) (13) (Reply)

Nigerian Naira Is Full Of Masonic Symbols / Jackie Chan In Saudi Arabia To Perform Hajj (photo) / What Can I Eat During White Fasting

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 71
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.