Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,152,977 members, 7,817,878 topics. Date: Saturday, 04 May 2024 at 09:53 PM

Ami Eranko Naa (yuroba, Nigeria; Mark Of The Beast Info) (pls If You Need A Bett - Religion - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Religion / Ami Eranko Naa (yuroba, Nigeria; Mark Of The Beast Info) (pls If You Need A Bett (3283 Views)

666 Aka The Mark Of The Beast: President Obama Vs Revelation 13:15-18 / Pray For Nigeria, Mark Tells Jerusalem Pilgrims / Pls If You Are Sick Or Troubled. Run To SHILOH Tonight (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Ami Eranko Naa (yuroba, Nigeria; Mark Of The Beast Info) (pls If You Need A Bett by Yefet(m): 9:29am On Aug 27, 2010
O si mu gbogbo won ati kekere ati nla oloro ati talaka, ominira ati eru, ki a fi ami kan fun won ni owo otun tabi ni iwaju won. Ati ki enikeni ma le ra tabi ta, bikose eniti o ba ni ami oruko eranko naa tabi iye oruko re. Nihin ni ogbon gbe wa, eni ti o ba ni oye ki o siro iye ti n be lara eranko naa, nitori iye eniyan ni iye naa si je ota le legbeta o le mefa.666 (Ifihan 13:16-18)



666 JE ETO AKOSO GBOGBO AGBAYE LABE IJOBA KAN SOSO



Ni bayi,. Awon ohun elo kan to n sise pelu ero ayara bi asa (konputa) to le se ise odiwon ni a ti sise lori re ti awujo wa si ti gba wole. Ohun elo kekere ti a n lo pelu konputa ti n lo imo ero ni a ti fi sinu awon ohun elo ti n lo ina, awon oja tita, awon nnkan osin ati eniyan. Eyi kii se imo sayensi ti ojo ola ti ko le sele, o n sele lonii.



Ni opolopo ibi ninu aye, imo ti n lo ohun elo kekere kan lati se awari aisan, arun opolo, ito suga, aisan ninu okan, ti o si tun n dena eniyan jiji gbe. Ni aipe, iru awon ohun to nii se pelu emi yii yoo di ohun ti gbogbo aye fe won yoo si fee maa gbe e sara fun idanimo, aabo ati itopinpin. eto oro aje ati awon iwulo ti a ko tii le ronu re.



O se ni laanu pe iru awon ohun elo yii maa n toju ohun idanimo enikan, awon ohun ti a si ri mu jade ninu lilo re ni a le fi pamo ki a si je ki o wa ninu ero ayara bi asa. Ara eniyan a wa di eyi ti a se ami si ti a si n topinpin re, ti a o si maa dari iwa iru eni bee.



Gbingbin ohun elo (microchip) si ara eniyan yoo yi iri eniyan, irorun re ati igbe aye eni bee pada. Wahala to n waye nipa lilo ohun elo to ni se pelu emi lara eniyan koja oro ewa, ilera, eto iselu tabi oro ofin.



Satani n sise ninu aye, o si n yi awon eniyan pada lati mu ipinnu re se. Boya a mo tabi a ko mo, asodi si Kristi yoo fi ipa mu awon eniyan lati tele e ati lati gboran si agbekale to dabii pe o wa fun anfani awon eniyan oun sugbon ni titele igbekale itan aye eniyan ati iselodi eniyan si Olorun yoo mu irora ati ijiya wa titi ti Kristi yoo fi pada wa.



O si n tan awon ti n gbe ori ile aye je nipa awon ohun iyanu ti a fi fun wa lati se niwaju eranko naa, o n wi fun awon ti n gbe ori ile aye lati ya aworan fun eranko naa ti o ti gba ogbe ida ti o si ye. A si fi fun un lati fie mi fun awon eranko naa ki o ma a soro ki o si mu ki a pa gbogbo awon ti ko foribale fun aworan eranko naa (Ifihan 13:14-15)



Asiko kan n bo nigba ti awujo ati awon eniyan yoo wa ni abe akoso ara eni ti a o ti maa topinpin eniyan ti a o si maa se alaye re, a o maa se odiwon re, ti ero ayara bi asa (konputa) yoo si maa se ayewo re. Ni gba yii, enikeni ti o ba ko lati gba ilana yii ni a o fi iya je, ti a o si pa.



IDASILE AWUJO TI O WOPO



A ti n lo si ipele awujo ti o bara mu, ti awon eniyan ni ipokipo yoo ti ni anfani si ohunkohun nibikibi ati nigbakugba lai ni fi se asiko tabi ibi ti won wa. Lilo imo ero ti n fi ise redio han ni awon ile itaja kekere je apeere kan . A se isiro pe opolopo awon oja ti a n ta ni yoo maa lo imo ero ti n fi ise redio han laarin odun kan tabi meji (lati odun 2005), won yoo si dipo awon ila ti a maa n fa si ara ohun ti a ra ti ero ayara bi asa (konputa) le ka eleyi ti a ti n lo fun ogbon odun seyin.



Ohun ti o n ti idagbasoke yii leyinn ni pe a o maa gbe igbe aye ti ko lewu, igbe aye to rorun, to ni oro ti o si se e gbadun nipa lilo imo ero to n sakoso igbe aye eni lojoojumo. Ni awujo to n pongbe fun eto isuna ti ero n sakoso re, ibara eni soro to ya kankan ati aabo, kii wa se ohun to le pe ti a o fi gba ki a fi ero to n sise pelu pelu radio si ni lara ti yoo si da owo ti a ti ji pada, tabi ti o sonu tabi eyi ti a pamo. Ni aipe ojo.



A o maa reti ki gbogbo eniyan ni ohun elo to n sise pelu emi. Gbogbo eto oro aje ni yoo maa lo ohun elo yii ti yoo si maa dipo bi a se n sewo.

1. Ko ni si ohun kankan ti o pamo mo, ominira ko si ni si mo.
2. Aladari kan ti o je asodi si Kristi yoo maa dari gbogbo aye nipa eto ti o je alatagba ti o si n kan ara won.

AMI ERANKO NAA NI ARA ENIYAN, A KO GBODO GBA A (Ifihan 14:9, 14:11, 16:2)

1. Gbigba ami yii je tita okan ara eni fun satani lai ni le ra a pada. Ese yii je eyi ti ko ni idariji, ti ko si se e yipada nipa ami naa (Ifihan 14:9-11) Olorun lo ni okan re. Nitori naa ti o ba gba ami yii, o ti di ti satani niyen.
2. Ti o ba gba ami yii, o n fi tifetife fi igbagbo re fun eniyan lai se Olorun. O ti yan lati gbe lai si Olorun ife to ni ipinnu lati lo ayeraye pelu re ni orun. Olorun ko fe ki o yan ona orun apadi. Olorun mo awon nnkan yii tele nitori pe o fe o, ti o si fe ki o mo eyi, a fi han wa ninu akosile Aposteli Johanu ninu iwe Ifihan ni ogorun odun leyin iku Kristi. Ti a ko ba mu o lo si orun ti a fi o sile fun ijiya, o ko gbodo gba ami eranko naa sibe a o je o niya, a o si pa o fun aigba ijoba ti satani n ddari re. O gbodo maa ranti eyi ni gbogbo igba nitori pe ireti orun si wa titi ti opin yoo fi de.

NJE O TI GBA JESU GEGE BI OLUGBALA RE?



Gbogbo eniyan lo sa a ti se ti won si kuna ogo Olorun (Romu 3:23)

Owo ko ni ohun gbogbo, eniyan ko le wa sodo Olorun nipa gbigbagbo ninu awon Olorun miran tabi igbekele eniyan, imo tabi rere sise. Ajosep[o pelu Jesu Kristi nikan lo le mu ki o se e se lati duro ninu ododo niwaju Olorun Mimo ni opin aye eniyan. Nitori idi eyi ni Jesu Kristi se jiya lori igi agbelebu, ti o ta eje re sile, ti o ku ti o si ji pada. Eleyi ni Olorun se lati fi ife re, agbara re ati ogo re nipa gbigba wa lowo ese ati iku.



Emi ni ona otito ati iye ko si eni ti o le wa si odo baba bi ko se ni pase mi (Johannu 14:6). Pe bi iwo ba fi enu re jewo Jesu ni Oluwa, ti iwo si gbagbo ninu okan re pe Oluwa jii dide kuro ninu oku, a o gba o la. Nitori okan li a fi a fi igbagbo si ododo, enu li a si fi ijewo si igbala. (Romu 10:9-10)

O gbodo gba Jesu gbo pe o ku fun ese re Jesu fe o niori ti Olorun fe araye to bee ge ti o fi omo bibi re kan soso fun ni ki enikeni ti o ba gba gbo ma baa segbe sugbon ki o le ni iye ainipekun. (Johannu 3:16). Ri ara re bi elese ki o si gbadura ninu igbagbo . O nilo lati gba Jesu ni olugbala re. Dajudaju orun wa, orun apaadi si wa. Jesu nikan ni ona si orun.



JESU N PADA BO MURA SILE FUN IGBASOKE

Jesu, eni ti o ra wa pada nipa agbelebu yoo pese ibi kan , yoo si pada wa lati wa pelu wa. O ti se ileri fun wa (Johannu 14:3) igbasoke yoo waye saaju wakati idanwo (Ifihan 3:10) Jesu wipe eyin le moye oju orun ati ti aye, sugbon eyin ko mo awon ami akoko wonyi (Mat. 16:3, Luku 12:56)



EYIN ARA MIMO NINU JESU KRISTI



Igbasoke je ohun ti a fi sile fun awon mimo ti a o gbe soke ni awosanmo nigba ti Olorun ba pe ipe, awon mimo ti a o gba soke ni a o gbe soke lati pade Jesu ni oju orun (1 Tessalonika 4:16-17) Igbasoke ni a fi sile fun awon onigbagbo ti o wo aso funfun ti emi. Ara won ni a o yi pada si ara ti ologo, yoo si je inu didun Oluwa. (Ifihan 19:7-cool. Ti o ba si wa ninu igbagbo ko gbona, ko tutu, Jesu yoo po o jade o ko gbodo dabi iru onigbagbo bi eyi (Ifihan 3:16) Wiwa Jesu akoko ni lati mu igbala wa, sugbon o n pada bo lati pade awon to se tan ti won si n duro dee ni awosanmo ni idahun si ipe, eyi ni a n pe ni igbasoke. Jesu Oluwa, yoo ko awon omo re pelu ara re lo si orun.Leyin wakati idanwo ninu aye, yoo tun pada wa si aye pelu awon ti a gba soke pelu re lo si orun lati lo si Jerusalemu titun, eyi ni a o pe ni Ipadabo re leekeji. Nitori kini ireti wa tabi ayo wa tabi ade isogo re? (1 Tessalonika 2:19)



Nigba ti Jesu ba pada de, awon eni mimo ti a gba soke nikan ni a o ko de iwaju ite ogo (1korinti 15:49-55). Bi a ti ko tile mo ojo ati asiko pipada bo re awon omo imole ko si ninu okunkun nitori naa ojo naa ko ni de ba yin bi ole. (1 Tessalonika 5:1-4). Nitori naa ranti bi iwo ti gba ati bi iwo ti gbo, ki o si pa a mo ki o si ronu piwada. Nje bi iwo ko ba sora, emi o de si o bi ole, iwo ki yoo si mo wakati ti emi o de si o. (Ifihan 3:3) Awon onigbagbo ko gbona ko tutu, awon ti a ti so mo aye ati awon ti ko mo Jesu ni a o fi sile fun wakati idanwo. Wakati idanwo yoo je igba eru julo ninu itan aye eniyan.Awon ti a fi sile ninu wakati idanwo ko gbodo gba ohun elo ti o ni se pelu emi (ti o ni oruko satani) si ara won (iwaju tabi owo otun Ifihan 13:16, 20:4) a ni de oju iku paapaa. Awon Kristeni to ba pa ara won yoo wa ninu ina titi ayeraye. Nipa kiko ohun elo yii, a o je o niya, a o si pa o fun awon alaigbagbo, kii se pe ki o ko ohun elo naa nikan, sugbon o nilati jewo Jesu ni Oluwa ati Olugbala re pelu enu re, ki o toro fun idariji fun ese re ki o si gbagbo ninu okan re pe omo Olorun ni ati pe o ku fun wa. Amin.
Comment · LikeUnlike · Share
Re: Ami Eranko Naa (yuroba, Nigeria; Mark Of The Beast Info) (pls If You Need A Bett by omoimole: 5:16am On Nov 17, 2010
My dear Yefet,

Pls can I speak to you in English. I am Yoruba and can and write the language fairly well. But if the purpose of this forum is to communicate, share and exchange a message, i am not sure if you are striking the right cords with members. I personally consider the topic 'Mark of the Beast' important, which some of us, particularly those of us 'Born Agains' are not paying attention to.

The Book of Revelations is almost a no-go area for many believers in Christ; and yet we are expected to study it and live by its message. The coming of Christ keeps getting nearer and nearer, but the Church seems oblivious. God will help us. Pls let's talk in English. It doesn't mean we dont respect our mother tongue. We do. More later.

Remain blessed
Maranatha

(1) (Reply)

12 Things You Love That Are Banned In The Bible / Did Jesus Ever Call Himself God In The Bible? The Answer Is No! / Jesus Lied

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 45
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.