Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,160,506 members, 7,843,523 topics. Date: Wednesday, 29 May 2024 at 07:23 AM

Se Gbogbo Wa Lobo Langido Ni? - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / Se Gbogbo Wa Lobo Langido Ni? (3108 Views)

Ogun Awon Bàba Wa / Sisigbeborun N Ki Gbogbo Mumini Ati Mumina Ododo Ku Odun O / To Lao Fe Fun Mi Lobo? (2) (3) (4)

(1) (Reply)

Se Gbogbo Wa Lobo Langido Ni? by obaede: 6:51am On Sep 30, 2014
Ale ana ki i n to sun, orin Bob Marley ni mo n gbo. Opolopo awon orin Bob Marley lo kun fun ogbon ati ijinle ede. Odun 1945 ni won bi Robert Nesta Marley ti gbogbo eniyan mo si Bob Marley ni Saint Ann to wa ni ilu Jamaica. Igba to pe omo odun merindinlogoji (36), ni odun 1981 lo gba ilu Amerika de ajule orun. Bi Bob Marley ko tile si laye mo, okiki awon orin to ti ko ko je ki oruko re pare.


Die lara ohun ti Bob Marley wi ninu awon orin re ni yii:

"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."

"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."



Bi eniyan ba le were titi ti were oun sare lo lai boju weyin, ti were ba de bi ti ona ti pin dandan ni ko yiju pada. Bi ilu Nigeria se ni ola to, ti eniyan kookan ni orileede Nigeria ba ni oko ayokele meta lagbala ko ti i poju. Sibesibe awon eniyan ko beere oko ayokele, aadota (50) naira ti won oo fi woko ni ko si lowo elomii. Owo iresi ogorun naira (100), ewa aadota (50) naira, ounje osan-an lai seran, ati piowota omi inu ora oni naira marun-un (N5) ni omo ogbon odun (30yrs) wa ti o fi jeun ti ko si lapo re. Agba to ji ti ko ba ooko ji, o ti ku won o ti gbe sin ni.



Awon eniyan ko beere oun to po rara, won ko tile gbero ati ko ile alarinrin bi eyi ti nbe ni Gwarimpa, Lekki tabi eyi ti won ko si Bodija n’Ibadan. Ohun ti won fe ni ibi ti won oo maa gbe ori won le to ba di lasaale.

Ori ti n fo awon odo ile yii, ohun to fa ori fifo ko si ye mi. Boya nipa iroyin owo bilionu aimoye ti n poora lojoojumo ti won n gbo seti tabi ise ti won ko rise ti won n wa kiri ti kosi nibi kankan lo fa efori tuulu. Sugbon ori n fo won gidi gan-an, owo iya won ni won si ti lo n gba owo fensiiki ti won lo lati dekun ori fifo abaadi. Sibesibe ori fifo o lo.



Ko si eni rere nibikibi. Yemi Elebuubon ti ni ‘Eeyan won, araye eniyan soro’. Eni afeyinti bi o ba ye wiwiniiwi. Eni a gboju okun le ko si jeni agba. Igi taa ba feyinti ka maa je igbadun, gbogbo ara lo fi segun. Eni o ye ko feni loju ti fata senu. Sebi igi taa tori re jiya, o ye ko le dana fun ni ya. Gbogbo awon olori wa pata ni odale, asise nla gbaa ni ominira taa gba lowo ijoba Biritiko je.


.
Kini anfaani ominira ti ara tun ni gbogbo mekunnu? Kini anfaani orogbo na? A pa ko lawe, a fi senu o tun koro bi jogbo. A tun ni ka figi re dana, won ni eewo ni enikan ki i figi orogbo dana. Orisa boo le gbemi fimi le bi mo ti wa. Bi ebiti ko ba peku o ye o le feyin feleyin. Bi eniyan ko si le jawe lori asewele a ki i ko tori re kuro.


http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html


Awon oba alaye ati ijoye ilu to ye ki won maa gba eto ilu lowo awon ijoba fun ara ilu ni won ti tori ijekuje so ori ade di yeyenatu. Enu to ba ti je dodo ko ni le sododo. Agbalagba to ba si so agbado modi, dandan ni ko di alawada adie. Agba ti o farabale ni i fara gbegba.


Mo nife orileede mi pupo gan-an, teni-n-teni, takisa n taatan. Omo eni ko ni sedi bebere ka wa fi ileke sidi omo elomii laelae. Ibi ori dani si laagbe. Sugbon odaju, eniibi, ika, ole, jaguda, gbewiri, olosa, barao, tiifu, wobia, alanikanjopon, onijekuje, ajeun-omo-nu-oyun, oloorun, onidoti, obun, olodo, akurari, olopo dudu, keferi alainiberu Olorun, apaayan ni gbogbo awon olori wa pata.



E je ka yopin loju ka fihan oju. E wo ni ki omo maa jale ka maa lomo n fewo. Baa wi aa ku, baa si wi orun la n lo. Baa sooto ba o sooto, o di dandan ki eye oko o fo lo.



Ojo ti mo gbo itan Tunde Fasasi (oruko re gidi ko ni yii), mo dupe lowo Olorun. Ti oloju kan ba ri eni ti o loju rara yoo sope fun Oluwa oba. Itan aroso ko, Isele to sele gidi ni. Odun karun-un re e ti Tunde ti n wase leyin to jade ile iwe. Igba ti o rise se lo lo ra aga ati tabili segbe titi lati maa fi se ise teliwaya.



O n ta kaadi ipe, eni to ba fe se eloelo ni gba muri kookan (N20) lowo won fun iseju kan ti won ba lo lori ila. Owo pensan baba Tunde ni won to papo mo owo ti iya Tunde ba pa nibi worobo ti fi n saje. Ireti won ni wi pe ti won ba fori ti titi, ti Tunde ba jade iwe yoo le ran aburo re lowo. Sebi ti okete ba dagba tan, omu omo re ni i mu. Ati wi pe tita riro laa kola, to ba jina ni i doge. Adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun birimu, imole lo kan. Sugbon riro ni teniyan, sise ni t'Oluwa oba. Se awa le so wi pe Oluwa oba ni ko je ki Tunde rise se, rara o.



Amukun eru re wo, oni oke le n wo e o wole. Baba Tunde saisan, awon ijoba o sanwo pensan kia, lojo kan ni Ogbeni Olarewaju Gbadamosi dake ti ko si ji mo. Ibi kan ni aburo Tunde obirin n gbe l'Abuja, won ni kojo omo odo tabi kabani sise ile ni i se nibi to wa loke oya. Ki i se wi pe o wu bee. Bi o ba r'adan, eniyan le fi oobe sebo.


http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html

Ko saa ma fi joko sile lasan ni. Iya o jeun, baba o jeun, won o tun sanwo ile. Bi eniyan ba n sare ki oju ma tini, ti oju ba ti tini are ka maa ku lo kan. Iduro o si, ibeere o si feni to gbodo mi. Igba to gbo iku baba re ni Morenike fi n pada bo nile. Se e mo awon olopa alaso dudu ti won maa tewo gba muri kookan ni masose? Awon ni won da oko ti Morenike wa ninu re duro. Awako ni i ba won lagidi ni won ni olopa ba yinbon. Olorun nikan lo ye bi ota ibon naa serin to fi ba Morenika lapa. Morenike o ku sugbon apa naa ko wulo fun-un mo.



Ko le pada si oke oya mo, joojumo ni won si n lo si osibitu lo gbatoju. Joojumo ni apa naa n ro Morenike. Awon kan tile ni boya aye ti toju bo egbo apa re ni ti ko fi jina lati ojo ti won ti n toju re. Oko iya Tunde ti ku, ise iya Tunde si ti doloogbe lowo bukata repete, joojumo ni Morenike n jerora. Gbogbo ebi lo ti salo fun won tori bukata. Kaluku lo kun un ru tie kiri. Temi gan-an tomi leru, e ma di kun-un. Oju titi ni Tunde si wa nibi to ti n gba muri kookan lowo eni ba fe se eloelo. Owo ti Tunde n pa ko to o jeun ka to wa so ebi to fi sile.




Mo mo omo gomina to ti je nigba kan ri to je wi pe gbogbo opin ose ni maa gbe baalu lo silu London lati lo wo boolu Premiasiipu ilu Oba, aa si pada wale lojo Aje. Ti o ba n lo, obirin meji ni i ko dani pelu awon ore re bi meta. Bakan naa ni mo ti ri aburo gomina kan ri to so wi pe oun o fi owo baye asobode ile itura kan je niseju mi korokoro nigba ti asobode naa so fun wi pe won kii to sibi ti n to si (aburo gomina naa ti mu oti yo nigba naa). Esi ti aburo gomina naa fun ni wi pe, “ maa fi owo ba ti e je”. E dakun, kilagbe ki le ju?


Bakan naa, mo ni ore kan to ti ni anfaani lati lo si awon ilu okeere bi meta tabi ju bee lo. Omo eniyan pataki ni. Awon Yoruba sibo, won ni ola abata ni i modo san, ola baba omo ni i mu omo yan fanda. Ore mi yi ti ni anfaani lati wo inu ile ijoba apapo l’Abuja - Aso Rock naa ri. Ojo kan lo so iriri re fun mi. O ni iru aye ti won je ninu ile ijoba apapo to wa l’Abuja, o ni oun ko ri iru aye bee nibikibi ni gbogbo ilu okeere ti oun ti de ri. O salaye die fun mi, emi gan-an yanu ni. Eni i sise wa ninu oorun, eni gbowo wa nibooji.


E je ki n tun pada sori oro Bob Marley Akoni igbaani,

"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."

"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."



Aifoonu eleyii ti won fi asan goolu gidi se n won ha ni saara lojo ti omo Aare n se igbeyawo alarinrin fun gbogbo alejo. Ilu Okeere bi meta ni oko ati iyawo tun fo de nikete ti ayeye igbeyawo won kase nile lati lo se onimuunu pelu opolopo owo dollar. Aimoye omo mekunnu ni won n ku lojoojumo loke oya, nigba ti awon kan tile sonu ti a ko ri won mo.



Akosile die ninu opolopo awon owo ti won ti ji ko pamo si ilu okeere nigba kan tele ni yii. Sampu lasan ni mo fi eyi se, eyi ti won ko pamo loteyii tun goboi. Se e ranti $9.3M ti won ri ni South Africa. Sebi eyi ti asiri tu lagbo, aimoye taa gbo nko?


Omo Aare to se igbeyawo ni yii saaju ko to lo si ile oko. Aimoye moto ni fi n se faaji, o si feran ko maa ko oruko inagije re si awon oko re gbogbo gege bi nomba. Awon kan tile so wi pe kii se omo bibi inu re gan-an wi pe o gbato lo wa so domo.


Iya n je opolopo awon eniyan o, eni ba ri ounje ojumo je ko dupe lowo Oluwa. Eniyan to wa ni alaafia ko mo ohun ti oju awon eniyan to wa ni osibitu n ri. Awon osibitu wa ko yato si ile iku, eni ori ba koyo ni i pada wale ti won ba lo. To ba je iro ni mo pa, kilode ti awon olori wa ki i se lo sibe (awon oba gan-an kii ya be).


Awon olopolo dudu ko ni won se yahoo-yahoo o, boya ti won ba ri ohun gidi fi opolo won se boya won ko ba jawo ninu ise ibi. Kosi omo ti o mowe, okun inu la fi n gbe tode. Ti omobirin ba ji ti n fidi re se sadaka kiri, e je ka ronu ka to fun iru obi omo bee lepe. Se ise asewo je ise ti eniyan mu yangan ni? Opo alagbara lo ti dole (laziness). Opolopo ologbon ni won ti domugo. Aimoye oku ni won rin ni titi bi alaaye sugbon oku ni won.


Mo nireti wi pe Nigeria yoo dun lojo kan. Mo si gbagbo wi pe abiku yoo di abiye. Sugbon e ba mi jise Bob Marley fun won. E so dorin titi yoo fi ko si won leti:

"You can fool some people sometimes, you can't fool all the people all the time."

"O le mu opo awon eniyan lobo fun awon igba kan, o ko le mu gbogbo eniyan lobo ni gbogbo igba."



Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Mo si feran orileede mi bi emi mi. Idi Pataki ti mo fi wa ni lati wa ki yin ku odun ominira. Mo ro yin ki e mu okan le gidi pelu igbagbo to jinle. O ni le koro, sugbon adun ni i gbeyin ewuro. Leyin okunkun imole nbo. Bi ekun pe dale ayo n bo lowuro. Kosi ohun to le ti kii ro. O di gba kan na! http://www.olayemioniroyin.com/2014/09/se-gbogbo-wa-lobo-langido-ni.html

1 Like

Re: Se Gbogbo Wa Lobo Langido Ni? by 2prexios: 5:43pm On Sep 30, 2014
Oluwa mi oro yin yi je oun edun ni okan mi. Lati igba ewe mi wa ni a tii nfi oju sona pe igba kan nbo ti orile ede ti o nsan fun wara ati oyin bii ti orile ede olominira ti a pe ni naijiria yi yoo dara. Bi ot ile je pe mo kere nigba ibo ati Ogun abele ti won pe ni June 12, igba yi ni awon oloshelu ti won laami laka nke gbajare kiri ode wipe nigba ti ijoba awa ara wa ba de, aye yoo tun daa de, igba a si derun fun koowa.

Emi sebi otito ni, nitori wipe a ro wipe oro naa yoo dogun nigba naa bi o ti nlo ni, amo won ni ka mokan, wipe gbogbo orile ede asiwaju l'agbaye la irufe aburu igba naa koja ki won to k'ogo ja. Amo o seni laanu wipe bi ojo tii ngori ojo ti osu si ngori osu, bee ni okanjuwa orile ede naijiria tunbo nyi bii awo erin, esi o.

Ah, iyalenu nla lo je. Ni igba atijo, awon babanla wa, ani awon agbagba oloselu ti won gbogun ti ijoba geesi wo ojo ola ti o dara ni iwaju won, won gbagbo wipe pelu imo ati ikora eni ni ijanu, awon yoo se orile ede yi ni okan gbogi laarin awon eya adulawo, awon yoo si se ni isogo awon orile ede Africa sugbon...omi teyin wogbin lenu.

O da naa, se bi a o ti maa baa lo na ni sa? Abi sise ku? A o ti maa woju Olorun pe to? Eledua o kuku nii fi sanmo sile lati wa yo wa ninu iyonu ti a fi se omi inira. Won ni "sanko sun, fake r'ori, oruko omo nii m'omo sokigbe" Se ko wa da bi eni pe Iya mbe ninu oruko orile ede yi sa, ti o fi je wipe awon Olori ati asiwaju koni oye isejoba lori eto idagbasoke?

To, mo soyi mo duro naa, nitori ti awon agba ba ngegi ni gbo, awon omode ni yoo mo ibi ti igi ohun maa wo si, to ba sesi wo pa asebi, iwonpapa, iwonna. E saa je ki amaa wa ninu ifura, nitori pe pansa o fura pansa ja, aja o fura aja jin, onile tii o fura ole ni yoo ko. Amo kin to maa lo, maa ran awon obayeje leti wipe.

Arise larika o, arika baba iregun, oun aba se loni o, itan ni o da b'odola. Ogun nii sini mu, epe kii sini ja: ojo esan o lo titi o joro o dunni.

(1) (Reply)

Indecent Dressing In Ladies / About The Itsekiris Of Delta State / Bini To English / V.v. Needed

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 54
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.