Welcome, Guest: Register On Nairaland / LOGIN! / Trending / Recent / New
Stats: 3,160,498 members, 7,843,514 topics. Date: Wednesday, 29 May 2024 at 07:11 AM

“asiri Iwa Ọwọ Femi Solar Ti Tu Si Mi Lọwọ” - Oniroyin - Culture - Nairaland

Nairaland Forum / Nairaland / General / Culture / “asiri Iwa Ọwọ Femi Solar Ti Tu Si Mi Lọwọ” - Oniroyin (1650 Views)

Asiri Aiye Siwa Lowo Awon Agba Woli / Asiri Ijinle Awon Woli Lailai / Asiri Ogun Awon Baba Wa (2) (3) (4)

(1) (Reply)

“asiri Iwa Ọwọ Femi Solar Ti Tu Si Mi Lọwọ” - Oniroyin by OlayemiOniroyin(m): 10:43pm On Mar 21, 2016
Ohun ti mo fẹ salaye nibi, mi o ko ohun to le ti ẹyin rẹ yọ. Asiri nla kan nipa iwa ọwọ Femi Solar ti ẹnikẹni seese ki wọn ma mọ ni mo fẹ tu jade. Yato si wi pe mo mọ ọ gẹgẹ bi gbajumọ olorin, ile emi ati ẹ ko jina sira wọn. To ba si jẹ eleyii ni yoo mu ajosepọ wa bajẹ, i don kia fiditi.

Sugbọn ki ni kan lo damiloju, eniyan ko ni gbin ẹpa, ko wa fi ka agbado. Ohun ti ẹda ba gbin ni yoo ka.

Femi Solar ọmọ Oladele maa gbọ, oni yii ni maa tu asiri iwa ọwọ re fun gbogbo araye pata.


Ti mo ba pari alaye mi tan, e le pe mi ni onilara, to ba wu yin, e le ni mo kan fẹ ba a loruko jẹ lasan ni. Iwọfa lẹnu, ohun to ba wu ẹlẹnu ni ko fẹnu sọ.

Lakọkọ na, mi o mọ ohun to ma n se bọbọ naa to fẹran lati maa tẹriba to ba n ki awon eniyan, atọmọde atagba lo ma n bọwọ fun nigba gbogbo. Tẹrintẹyẹ lo fi n ki gbogbo ẹni to ba pade lọna. Ẹmi irẹlẹ rẹ dabi ẹni ti n sise Oluwa, bẹẹ ise orin nise rẹ.

Bawo ni olorin yoo se wa ti oju rẹ yoo ma tutu nigbogbo igba? Awon olorin temi gbadun swagger wọn, tajutaju ni won fi n gbera. Oju won a ranko bi oju amọtẹkun, oju won a pọn bi ẹrẹyin, a wa maa sana sarasara bi tina ilagbẹdẹ.

Sugbon ti Femi Solar ko ri bẹẹ, ki i binu ki i ja, ki i kapa soke gangan bi bọọda mi oke ohun oniṣeeni janganna lọrun. Awọn asiri iwa ọwọ Femi Solar ni yii.

Ti oun ati awon ọmọ rẹ ba ti ode ere de tabi ti won ba n mura lati lo kọrin, o fẹran lati ma ba awon ọmọṣẹ rẹ sere pupọ. To ba n sere pelu wọn, agidi ni eniyan yoo fi mọ ọga yato si ọmọsẹ. Won jọ maa n lọ pọfupọfu gba mọ ara won lọwọ ni. What a palapala ilu apala! (ẹ ma binu pe mo so oyinbo jare, bọbọ yẹn lo kọs ẹ).


Ẹniwee, Jasa orin Solar ti doorun ti ko se fọwọbo mọle laelae. Oore ọfe atokewa Oluwa lo ye ki gbogbo wa o beere fun. Aanu Oluwa rekọja ohun gbogbo, ohun nikan lo si le mu ni di alaseyori. Lọjọ kẹwaa osu kerin odun yii, lala o lu!
10-04-2016


Femi Solar yoo ma se ifilọlẹ fidio orin GRACE ati awo orin tuntun rẹ to pe ni MERCY BEYOND ninu gbongan nla ti Genesis to wa nibadan nile Oluyọle. Aimoye awọn olorin ni wọn yoo pejupese sibẹ lati ko awon orin tuntun naa jade bi ọmọ tuntun jojolo. Funfun lẹyẹ n su, ẹ wọ asọ funfun wa pade Solar, o da mi loju wi pe, ọjọ naa yoo larinrin yoo si miringindin. #GbaBẹẹ

http://www.olayemioniroyin.com/2016/03/asiri-iwa-owo-femi-solar-ti-tu-si-mi.html

Re: “asiri Iwa Ọwọ Femi Solar Ti Tu Si Mi Lọwọ” - Oniroyin by tpiar: 12:16am On Mar 22, 2016
WHO IS THIS ONE AGAIN NITORI OLOUN?

NIBO NI WON TI NKO YIN WA GAAN?
Re: “asiri Iwa Ọwọ Femi Solar Ti Tu Si Mi Lọwọ” - Oniroyin by enigstil(m): 6:14am On Mar 22, 2016
I tire o.See as he let me waste my time.

(1) (Reply)

Have You Heard A Yoruba Man Singing With A Touareg??? / The African Tuareg Islamic tribe where men wear the veil instead of women! / Ikwerre, Igbo And The Igboid Language Family.

(Go Up)

Sections: politics (1) business autos (1) jobs (1) career education (1) romance computers phones travel sports fashion health
religion celebs tv-movies music-radio literature webmasters programming techmarket

Links: (1) (2) (3) (4) (5) (6) (7) (8) (9) (10)

Nairaland - Copyright © 2005 - 2024 Oluwaseun Osewa. All rights reserved. See How To Advertise. 12
Disclaimer: Every Nairaland member is solely responsible for anything that he/she posts or uploads on Nairaland.